Igbákejì olórí orílẹ̀èdè yí, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọsinbajo, ti fìdùnú rẹ hàn sí bí ìwà lásígbo akọsákọ òhun abosábo se ń díkùn nípasẹ̀ ìdásí àwọn asáàjú àwùjọ àtàwọn olórí ẹlẹ́sìnjẹsin nílẹ̀yí.

Ó sọ̀rọ̀ náà nílu Abuja lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ níbi è[tò kan tó wáyé.

Ọjọgbọn Ọsinbajo tí alákoso fọ́rọ̀ àwọn obìnrin, Dame Pauline Tallen sojú fún wá rọ àwọn asáàjú àwùjọ àtàwọn adarí ẹ̀sìn láti ri dájú pé, òfin tó rọ̀mọ́ ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé di sásàmúlò láwọn ìpínlẹ̀ mẹ́wa tókù.

Sultan tìlú Sokoto Alhaji Saad Muhammed saad ti ise alága ètò ọ̀hún wá àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn asáàjú àwùjọ lẹ́kùn àríwá níwájú láti dábo bo àwọn ọmọbìnrin pẹ̀lú ọ̀kan-ọ̀jọ̀kan àgbékalẹ̀ òfin láwọn agbègbè.

Nínú ọ̀rọ̀ igbákejì akọ̀wé àjọ ìsọ̀kan àgbáyé, Hajia Amina Muhamed, lóti sàlàyé pé àsà lágbayé fún ọmọdé, ìgbéyàwó ipá, tó fi mọ́ abẹ́ dídá àtàwọn ìwà min ń gogò láwùjọ nítorí àrùn Covid-19 tó ń fi ìlú lògbòlògbò.

Lara Ayọade/Ayodele Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *