Yoruba

Aare Buhari Setan Lati Sin Awon Iko Ile Nigeria Ninu Idije Tokyo Olympic Soko

Ojo Aje Monday to nbo yii ni Aare Muhammadu Buhari yio gbe awon iko elere idaraya tile Nigeria, to nlo fun idije Tokyo Olympic lalejo nile ise Aare to wa nilu Abuja, koto dipe awon isi togbehin awon io ohun yio gbera kuro lorile ede Nigeria lo sibi eto idije naa.

Alakoso foro awon odo ati idagbasoke ere idaraya nileyi, Ogbeni Sunday Dare, lo so oro ohun di mimo nilu Abuja, lakoko tiwon nse ayeye idagbere ranpe fawon isi akoko awon iko elere idaraya naa kiwon to gbera losi orile ede Japan.

O sope awon iko ohun niwon yio gbera ni isise ntele nipele merin, ni Aare Buhari yio se ikini idagbere fun lojo Aje to nbo gegebi ara asa ati ise ileyi fawon elere idaraya.

Alakoso ere idaraya ohun tun salaye pe ayeye naa yio tun fun Aare lanfani lati fa waon iko elere idaraya tile Nigeria fun awon igbimo idije Olympic ni ibamu pelu botiwa lati ojo pipe wa.

Ogbeni Sunday Dare, tun safomo oro pe Aare Buhari yio tun safihan aso idaraya toje tawon iko elere idaraya ile Nigeria to nlo fun idije Olympic.

Ni bayina orileede England niyio ma wako pelu orileede Denmark labala tokangun si ase kagba idije ere boolu alafesegba Euro 2020 to n lo lowo.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *