Yoruba

Igbakeji Gomina ipinle Oyo, Onimo Ero Rauf Olaniyan lo soro idaniloju naa nibe eto ayeye odun ofin fodun 2021 si 2022 eleyi to waye ni Mosalsi nla Oja’Ba nilu Ibadan.

Onimo Ero Olaniyan sope awon yoo ri daju pee ka eto idajo n sise won laisi idiwo Kankan latowo eka alase pelu afikun pee ka alase koni desi oro gbogbo toba ro mo igbejo bi ti wu ko mo.

Eni tiise adajo agba ipinle Oyo,  Adajo Munta Abimbola wa gboriyin fun eto isakoso Gomina Seyi Makinde fun igbese to fa gbigba adajo merin tuntun si pelu idaniloju pe adajo mefa min yoo di yiyan sipo laipe.

Ko sai se lalaye pe ogba atunse eleyi ti yoo maa risi eto idajo omode yoo se didadile kole sise lori eto igbejo molebi

Ayodele Olaopa

Yoruba

Ijoba Ipinle Oyo ti bere eto idanileko fawon Kanselo to to oodunrun ati mokanlelaadota pelu awon akowe metalelogbon to je ti ile asofin ijoba ibile.

Eto idanileko naa lo da lori liana isejoba rere nijoba ibile ati idesemulle liana asotele onikoko merin ijoba to wa lode nipinle Oyo.

Nigba to n side ero idanileko naa, Oludamoran Pataki fun Gomina lori oro ile asofin, Ogbeni Samuel Adejumobi salaye wipe, won gbe eto idanileko naa kale lati fi lawon loye nipa ofin ati eto atunto to n waye nileese ijoba apapo ati ipinle ati liana amuse won ninu eto onikoko merin isejoba Gomina Makinde lawon agbegbe esekuku.

O ro won pe ki won fi tokan-tokan se ise iriju won nipa amuse liana onikoko merin ijoba.

Babatunde Salaudeen

News Yoruba

Ijoba ipinle Oyo ti funle igbese kiko awon alagbe kuro nibi ti won pejo si lopopona Jenbewon, lagbegbe Sabo nilu Ibadan lo si aaye tuntun ti won pese fun won lagbegbe Akinyele.

Igbese naa ti won bere lait bii osu melo kan seyin ni won side re ni sansan laaro oni, leyin ti awon asaaju awujo Arewa ati asoju awon alagbe naa ti se abewo si ibudo tuntun naa lojo abameta ko koja yi.

Alabojuto oro ayika, Amofin Idowu Oyeleke, eni ti saaju ibi akoko awon alagbe naa lo si Akinyele salaye wipe opo nnkan amayederun ni won pese si ibudo naa ti, ileewe, ilee iwosan ati aaye igbafe.

Atejade ti akowe iroyin fun Gomina Seyi Makinde,iyen Ogbeni Taiwo Adisa fi sita deke awon ileese, oioba ti lowo ninu igbese naa bii ileese ti nri soro awon obinrin ati irin ajo afe, ileese oro ijoba ibile ati oye jije to fi mo ofiise akowe ijoba ipinle Oyo pelu ajo eleto aabo, eyi ti alamojuto ileese olopa nigba kan ri Ogbeni Fatai Owoseni je olori fun.

Ekun oko elero ijoba nla taa mo si pacesetters bus meta lo ti ko awon alagbe naa lati opoppona Jenbewon lo si agbegbe Akinyele ti awon mii si tun n ko won lowo.

Kehinde/Saludeen

Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti so di mimo pe ijoba re yoo se asepo pelu ajo to n ri si idagbasoke oja kiko sowo soke okun , NEPC, lona ati sogba pelu awujo agbaye nidi oja kiko sowo sile okeere.

Gomina se asoyan oro yi lasiko abewo si oludari ajo naa, Oloye Olusegun Awolowo se sodo re nilu Ibadan.

Gomina eni to akowe ijoba ipinle Oyo Arabinrin Olubamiwo Adeosun soiju fun tenumo pe Ijoba Ipinle Oyo ti mu agbega ba ise agbe di aladanla nilana igbalode.

Gomina  salaye wi pe ijoba re ti se atunse opolopo ona lagbegbe igberiko lona ati mu igbe aye rorun fawon agbe.

Ninu oro re, oludari agba ajo ton ri si ipolongo oja kiko sowo sile okeere , NEPC, oloye olusegun awolowo pe fun ajosepo to dan moran pelu ajo naa fun ipese ise.

Oloye Awolowo tenumo pe ajo naa yoo se ise po pelu Ijoba Ipinle Oyo lati fi mu igba otun ba Oja Okerete to wa nilu Saki tii se enu aala ile yi fun anfaani awon eeyan Ipinle Oyo.

Adebisi/Salaudeen

Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimoero Seyi Makinde ti seleri ati mu adinku ba iku alaboyun ati omo wewe, pelu mumu agbega ba eto ilera alabode pelu ida ogota.

O soro yi di mimo lasiko to n se ifilole akanse eto ilera olomo wewe to da pe ni tomotiya.

Gomina Makinde, eni ti igbakeji re Onimoero Rauf Olaniyan pelu alaye pe akosile ti se afihan re pe ipinle Oyo maa n foju wina iku awon omo ikoko julo lorileede yi, eyi lo je kijoba to wa lode se agbekale akanse eto tomo-tiya.

Gomina se afikun re pee to naa yoo rii daju pe idagbasoke to loorin ba eto naa fun ipese eto ilera to pegede fawon alaboyun.

Saaju ninu oro ikini kaabo re, alakoso eto ilera nipinle Oyo, Dokita Bashir Bello salaye wi pe, yato fun ipese ilera to peye fun iya ati awon ome wewe, eto yi yoo tun seto adejutofo fun alaboyun. 

Ninu oro re eni to se agbekale eto Tomo-tiya, to tun je oludamoran Pataki fun Gomina lori eto ilera, Dokita Funmi Salami salaye wi pe ijoba ibile meta otooto ni eto naa yio ti koko bere.

Idogbe

Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti bere eto ikole ojule toto otaleloodunrun ti owo re to billionu meji abo naira ni Ajoda lati rii wipe ileegbe toto wa fun awon omo Ipinle yi.

Eto ikole naa ti yio wa lori saree oko metala ni Ijoba Ibile Egbeda je ajumose ile ise aladani ati ijoba.

Gomina Makinde tenumo wipe o se Pataki lati pese ile gbe alaboode fun awon eniyan ilu yi npo si pelu ida meji lati odun 2018.

Gomina Makinde seleri wipe gbogbo awon eto ikole to nlo lowo nipinle yi ni won yio sagbeyewo to wa fi da awon oludokowo loju wipe won yio janfani ayika ti aabo re peye.

Saaju ninu oro re, Alaga ajo to nrisi oro ileegbe nipinle Oyo, Ogbeni Bayo Lawal tenumo ipinnu ijoba to wa lode lati mu iderun baa won eniyan nipa ipese ilegbe to dun wo.

Alakoso foro ile ati ilegbe nipinle yi, Ogbeni Abiodun Abdulraheem ro awon oludokoowo ati awon olugbe ipinle yi lati je anfani eto alailegbe yi.

Adebisi/Dada

Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sọpé láipẹ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ yóò ma jànfàní ilé-tóworẹ̀ ògajaralọ nípasẹ̀ okòòwò pẹ̀lú ìjọba àti aládani láipẹ.

Alága, àjọ tó ńrísí ilé-ìgbé nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, olóyè Bayọ Lawal sọ èyí lásìkò tó ńkopa lórí ètò ilésẹ́ Premier F.M lédè gẹ́ẹ̀si Straight Talk.

Olóyè Lawal sàlàyé pé, ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti ńsisẹ́ tọ́ọ̀ ìdúnadúrà pẹ̀lú àwọn òsìsẹ́ aládani méjìlélógún, láti kọ́ọ̀ ilégbe ọ̀tàalélọdúrún.

Ọga àjọ tónrísí ilégbéè, sọpé ìgbésẹ̀ tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ dahun,ibere àwọn aráàlu tán, èyí tóòmú fojúhàn pé, ìjọba kòlè nìkan pèsè ilégbe fàwọn aráàlu rẹ̀.

Olóyè Lawal wá fikun pé, ójẹ́ òun tóbanilọ́kànjẹ wípé bíì igbaa ẹkaa ilẹ̀ tójẹ́ tìjọba lágbègbè ìgànná tijẹ́ títọwọ́bọ̀ nítorí àisàmúlòrẹ̀ fún isẹ́ ilégbe tóòyẹ.

Elizbeth Idogbe  

Yoruba

Pelu bi awon toni arun Covid-19 ti se n posi nile yii, Gomina Ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde ti fofinde agbekale eto isin gbogbo, ayeye igbeyawo, ayeye yoowu tabi isinku fose meji.

Bakanna, Gomina tun pase pe gbogbo awon ibudo igbafe gbodo je titipa leyeosoka.

Gomina Makinde, enito soro yii lakoko to n baa won eniyan soro lori ero igbohunsafefe nilu Ibadan, tenumo pe akojopo awon eniyan kogbodo ju ogbon tabi komatobe lo.

Pelu alaye pe ipade apero awon awakusa to ye kowaye gbodo je sisun siwaju tofimo apero awon agbe lati pinwo arun Covid-19.

Nigba to un salaye pe kosi on to poju lati se gege bi ona lati pinwo arun Coronavirus, Gomina Makinde rawo ebe si gbogbo awon tase naa ba kan lati ri gegebi ona ifira-eniji fun ile baba eni lati dena iku aitojo nipinle Oyo.