Yoruba

Ìgbìmọ̀ alásẹ ìjọba àpapọ̀ ti buwọlu isẹ́ àkànse mẹ́rìndílógún lójúnà àti mú àgbéga báà iná mọ̀nà-mọ́ná nílẹ̀ yíì.

Alákoso fóun àmúsagbára, Àlhájì Abubakar Aliyu sọ̀rọ̀ yíì fáwọn oníròyìn lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ alásẹ èyítí igbákejì ààrẹ ilẹ̀ yíì ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Osinbajo darí rẹ̀ nílu Abuja.

Ó níì ìpèníjà kan gbogi tó ńkojú ìdúró ree iná mọ̀nàmọ́ná nílẹ̀ yíì ní kíkùnà nídi pínpín iná mọ̀nàmọ́ná tówànílẹ̀ lọ́nà tóyẹ.

Alákoso ọ̀ún tọ́kasi pé, ibùdó apako pin soso lówà nílẹ̀ yíì níbití wọ́n ti kaseyọri le ba ẹ̀ka wọn.

Elizabeth Idogbe

Yoruba

Ijoba apapo ti sope ohun ti se ifilole okan-o-jokan eto lawon ekun idibo mefeefa to n be nile yi ki amuse le deba adehun pipose ina oba fun milionu marun idile pelu itansan oorun titi odun 2023.

Igbakeji Aare ileyi, Ojogbon Yemi Osinbajo lo soro naa lasiko to n siso loju ipade apero lori oun amusagbara nilu Abuja. Ojogbon Osinbajo ti alakoso keji foro ayika, Arabinrin Sharon Ikeazor soju fun, salaye pe igbiyanju naa lo wa ni ibamu pelu eto toro mo oun amusagbara.

O sope eto ohun ni yoo lapa lara apapo milionu meedogbon omo ileyi pelu pipese ise fun egberun lona otalerugba odin mewa eyan.

Ewe, eni tiise oga agba ile ise elepo robi nileyi, Malam Mele Kyari sope ile ise naa ni yoo ma ate siwaju lori atunse eka ohun amusagbara ile yi.

Ayodele Olaopa

News Yoruba

Igbimo kan to ni ninu, awon asoju ile ise ijoba, lajolajo, egbe awon osise NLC, ati TUC ni won ti gbe kale lati sise lori ekunwo owo ina oba bere lati oni yi lo.

 Igbimo yi ni ireti wa wipe yio sise fun ose meji.

Alakoso foro awon osise ati igbani sise nile yi, Ogbeni Chris Ngige lo sore yi nigbati, o nka atejade ipade ti won fi sita leyin ipade lati yanju aawo laarin egbe awon osise ati ijoba to waye nilu Abuja.

O salaye wipe igbimo naa yio sagbeyewo idi ti liana tuntun naa fi se Pataki lojuna ati woo boya idi ti won fi gbe liana tuntun naa kale fesemule.

Alakoso naa ni lori oro to nlo salaye wipe ijoba yio wa ona lati ro owo ori to gun owo osu tuntun gegebi ona lati mu adinku ba ipa ti liana naa ni lori awon omo ile ye.

Nibayi naa, egbe awon osise ti so iyanselodi ti npero re nitori ekunwo owo epo ati ina oba ro fun ose meji.

Adesanya/Dada