Yoruba

Ijoba Apapo n gba lero ati pese ina oba fun milionu marun idile

Ijoba apapo ti sope ohun ti se ifilole okan-o-jokan eto lawon ekun idibo mefeefa to n be nile yi ki amuse le deba adehun pipose ina oba fun milionu marun idile pelu itansan oorun titi odun 2023.

Igbakeji Aare ileyi, Ojogbon Yemi Osinbajo lo soro naa lasiko to n siso loju ipade apero lori oun amusagbara nilu Abuja. Ojogbon Osinbajo ti alakoso keji foro ayika, Arabinrin Sharon Ikeazor soju fun, salaye pe igbiyanju naa lo wa ni ibamu pelu eto toro mo oun amusagbara.

O sope eto ohun ni yoo lapa lara apapo milionu meedogbon omo ileyi pelu pipese ise fun egberun lona otalerugba odin mewa eyan.

Ewe, eni tiise oga agba ile ise elepo robi nileyi, Malam Mele Kyari sope ile ise naa ni yoo ma ate siwaju lori atunse eka ohun amusagbara ile yi.

Ayodele Olaopa

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *