News

Àjọ tó rísí ètò ìlera nípinll Èkó sọpé, ohun ti ńgbé ìgbésẹ̀ láti sàfikún àwọn olùgbé tóòtóò milliọnu mẹ́ta sínú ìlànà ètò ìlera adójútófo ti ìforúkọsílẹ̀ náà yóò sì wáyé lárin ọdún kan.

Alákoso àgbà fájọ ọ̀hún Dókítà Emmanuẹla Zamba, sọ èyí di mímọ̀ níbi ìpàdé ètò ìlanilọ́yẹ̀ àwọn èèyàn ẹsẹ kùkú àti ìgbésẹ̀ iforukọ sílẹ̀ tó wáyé nípinlẹ̀ náà.

Díkítà Zamba ẹnitó sàlàyé pé, ètò ìlanilọ́yẹ̀ àti iforukọ sílẹ̀ ọ̀hún sepàtàkì nítirípé ìlera lọrọ̀ àtọ́kasí.

Àwọn irinsẹ́ toye pe okolerugbaole méjì ló ti wan kanlẹ láti sètò iforukọ sílẹ̀ ná. Elizabeth Idogbe

Yoruba

Ijoba ipinle Eko ti so pee to iranwo eyi ti banki Agbaye gbe kale lati mu kagbega deba akowo ati igbaye gbadun araalu, ni yo se atileyin fun ise akanse kilo opopona to wo oko to le ni ibuso agbegbe oko merin otooto.

Alakoso feto ogbin nipinle Eko, Arabinrin Abisola Olusanya, lo je koro yi di mimo ni ikeja.

Arabinrin Olusanya so pea won agbegbe oko mereerin naa ni Igbodu nilu Epe, Araga to ni Epe bakanna, Erinkorodu nilu Korodu to fimo Afowo ni Badagry.

O tokasi pea won onl ero ti bere ise lori opopna mereerin lati mo pato iye ti won yon na lee lori ti ise yoo sib ere leye o soka.

Afonja

Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti sọpé gbogbo òpópónà àti afárá èyí tí wọ́n ńkọ́ lọ́wọ́ ládugbò Apapa ni yo jẹ píparí nínú osù kẹwa ọdún tawàyí.

Gómìnà Babajide Sanwo-olu ló sọ̀rọ̀ ìdánilójú yi lásìkò tó se àbẹ̀wò láti mọ ibi tísẹ́ dé dúró lágbègbè náà, n’ípinlẹ̀ Èkó.

Gómìnà Sanwo-olu, sọpé súnkẹrẹ f’àkẹrẹ ọkọ̀, tón f’ojúmọ́ faye lágbègbé náà, ni yó di àfìsẹ́yìn tégún fisọ nígbàtí àwọn isẹ́ àkànse ọ̀hún bá jẹ́ píparí.

Lára ibi isẹ́ àkànse tí Gómìnà sàbẹ̀wò sí látirí afárá constain, Marine, Ijọra tófimọ́ agbègbè Liverpool, Lillypond àti Mile 2.

Ó ní isẹ́ àkànse yi se pàtàkì láti jẹ́ kí agbègbè dé bá, agbègbè Apapa l’ápapọ̀, kí lílọ bíbọ̀ si lè já gara.

Ọlolade Afọnja

Yoruba

Gomina Ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ro awon olugbe ilu Eko lati se suuru lori isoro ti won yio foju wina re laarin osu mega ti won fe fi ti abala kan afara 3rd Mainland bere lati oni lo.

O  soro yi lasiko ti o ngbalejo oga ajo eso oju popo FRSC tuntun nipinle Eko, Ogbeni Olusegun Ogungbemide ni ile ijoba to was ni Marina.

Gomina Sanwo-Olu wa seleri fun awon omo ile yi wipe isoro die ni won yio koju nitoriwipe awon osise ajo to nrisi igbokegbodo oko nipinle Eko LATSMA ni won yio ko lo sawon oju popo lati maa dari oko.

O ni titi afara yi ti opo oko maa nrin ni ko see ye sile nitoripe o ti ngbo layiti ayewo ti ijoba apapo se fihan.

Gomina Sanwo-Olu ni ijoba ti satunse awon ona miran ti awon eniyan lee rin lari lee muki lilo bibo oko tubo rorun.

Nigbati o nfesi, Ogbeni Ogungbemide ni ajo FRCN yio fowosowopo pelu ajo LATSMA lati bojuto lilo bibo oko nipinle naa.

Yemisi Dada