Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ èkó sèlérí pé isẹ́ àkànse kíkọ́ òpópónà apapa yo parí nínú ọdún yí

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti sọpé gbogbo òpópónà àti afárá èyí tí wọ́n ńkọ́ lọ́wọ́ ládugbò Apapa ni yo jẹ píparí nínú osù kẹwa ọdún tawàyí.

Gómìnà Babajide Sanwo-olu ló sọ̀rọ̀ ìdánilójú yi lásìkò tó se àbẹ̀wò láti mọ ibi tísẹ́ dé dúró lágbègbè náà, n’ípinlẹ̀ Èkó.

Gómìnà Sanwo-olu, sọpé súnkẹrẹ f’àkẹrẹ ọkọ̀, tón f’ojúmọ́ faye lágbègbé náà, ni yó di àfìsẹ́yìn tégún fisọ nígbàtí àwọn isẹ́ àkànse ọ̀hún bá jẹ́ píparí.

Lára ibi isẹ́ àkànse tí Gómìnà sàbẹ̀wò sí látirí afárá constain, Marine, Ijọra tófimọ́ agbègbè Liverpool, Lillypond àti Mile 2.

Ó ní isẹ́ àkànse yi se pàtàkì láti jẹ́ kí agbègbè dé bá, agbègbè Apapa l’ápapọ̀, kí lílọ bíbọ̀ si lè já gara.

Ọlolade Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *