Yoruba

Adari eto iroyin nileese Oloogun ile yi, Major General Benjamin Sawyer ti bere fun ajosepo pelu ileese Radio Nigeria nidi eto ironilagbara fawon osise re nipe iroyin gbigbe jade lori aseyori ileese ollogun lona ti aabo to peye yoo fi w anile yi.

O pe ipe yi nilu Abuja lasiko to saaju iko awon osise re lenu abewo solu ileese Radio Nigeria, lati se enle n beun si oludari agba ileese Radio Nigeria, Omowe Mansur Liman.

Ogagun Sawyer gbosuba fun leese Radio Nigeria nipa eto ironilagbara fun ileese Radio to je tileese ologun eyi to wa nilu Abuja, o wa pe fun itesiwaju ati ajosepo naa.

Nigba to n fesi, oludari agba ileese Radio Nigeria, Omowo Mansour Lima seleri igbaradi ileese, Radio Nigeria lati je ki ogagun naa se aseye talakan n sepo pelu pipolongo igbokegbodo ilees, oloogun fun isokan ile yi.

Babatunde Salaudeen

News Yoruba

Ajo eleto ilera lagbaye, WHO ti ni ona ti Orile Ede Naijiria ngba bojuto ajakale arun Covid 19 o wa nipo kerin agbaye.

 Asooju ajo who nile yi, Ogbeni Walter Mulombo lo soro yi nibi eto kan to waye bi won se tewo gba abere ajesara Covid 19.

Johnson and Johnson to to egberun lona metadinlogosan o le niye to waye nilu abuja.

O ni ona ti  orile eded yi ngba bojuto arun covid 19 ni o je okan lara awon onato jafafa julo lagbaye.

Gege bi ogbeni Mulombo se so ajo who ti gboriyin fun  ile yi lopo igba laiyo igbimo amuseya ijona apapo ile  ise ijoba  apapo foro ilera ati ajo to mbojuto ile iwosan alaabode sile fun aseyori won lori fifun awon eniyan labere ajesara Covid 19 ni ipele akoko se.

 Ni ti e, asoju ajo UNICEF, Peter Hawkins ro awon asaju esin ato awon lobaloba lati se koriya fawon eeyan lati gba abere ajesara Johnson and Johnson.

Oluwayemisi Owonikoko

Yoruba

Àjọ tó ń rí sí ìpeniye ǹkan ìlò nílẹ̀ Níajírìa SON, ti sèkìlọ̀ fáwọn iléésẹ́ tó ń pèsè irin pé kí wọ́n mójútó àwọn irin-isẹ́ tí wọ́n ńlò fún ìpèsè irin.

Olùdarí àgbà àjọ SON, ọ̀gbẹ́ni Farouk Salim tó sípayá ọ̀rọ̀ yí níbi àpéjọpọ̀ kan tó wáyé nílu Abuja sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé àjọ náà ti se àlàkalẹ̀ ìlànà lórí irin-isẹ́ tí wọ́n gbọdọ náà tẹlẹ.

Ó tọ́ka si pé àjọ SON kojú osuwọn láti máà se atọ́nà lórí iri-isẹ́ tí wọ́n gbọdọ̀ máà lò láwọn iléèsẹ́ bíì èyí ti ń pèsè irin-tutu, iléèsẹ́ ojú omi pẹ̀lú iléèsẹ́ èròjà epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsi.

Ọgbẹni Salim tún sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé gbogbo ǹkan ti wọn fi ń se òdiwọ̀n àti àwọn irin-isẹ́ tí wọ́n ń lò níléèsẹ́ tó ń pese asọ ni wọn gbọdọ máà tọpinpin wọn, kí ohun gbogbo le máà lọ déèdé.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Banki agbaye ti buwolu owoya oni millionu eedegberin o le ni aadota, 750 million dollars ti egbe to wa fun idagbasoke lagbaye fun agbedide eka ina oba nile Naijiria.

Ninu atejade ti banki naa fi sita nilu Abuja, o ni igbese naa ni won gbe lati lee ri pe eka ina oba tubo fese rinle ki won si lee ko akoyawo.

Atejade naa salaye wipe ida metadinlaadota awon omo ile yi ni won ni anfani si ina oba nigbati awon ti won nni nkoju idakuruku ina oba.

O fikun wipe, sisatunse si eka ina oba ni paapajulo fun awon eka to npese nkan nile yi se pataki lati muki oro aje tubo gbooro sii leyin ajakale arun Covid-19.

Yemisi Dada