Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti sèlérí milliọnu kọ̀kan naira fẹ́bí àwọn tó sọ ẹ̀mí won nù nípase aawọọ ìbọn yínyìn lárin àwọn òsìsẹ́ ẹ̀sọ́ asọ́bọdè àtàwọn onífàyàwọ́ to waye nílu Ìsẹ́yìn.

Ó sèlérí yíì lásìkò tó sàbẹ̀wò sáfin Asẹ́yìn ti Ìsẹ́yìn, ọba Abdulganiu Adekunle.

Gómìnà Makinde ẹnitó bẹnu àtẹ́lu ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ni ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ yóò gbé ìgbésẹ̀ ìwádi tóòyẹ.

Ó wá rọ àwọn aráàlu Ìsẹ́yìn láti fowọ́ wọ́ọnú kíwọ́n sì fòpin sí àawọò tólè sokùnfà òfò ẹ̀mí àti dúkia nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Gómìnà Makinde wá fọwọ ànfàní ìjọba àwarawa fáwọn èèyàn Ìsẹ́yìn sọ̀yà, tó sì sèlérí àtúnse komonkia ọ̀nà Ìsẹ́yìn soyo àti Ìsẹ́yìn Ogbomọsọ ki ètò ìsèjọba rẹ̀ tó paríì.

Elizabeth Idogbe

Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti so di mimo pe ijoba re yoo se asepo pelu ajo to n ri si idagbasoke oja kiko sowo soke okun , NEPC, lona ati sogba pelu awujo agbaye nidi oja kiko sowo sile okeere.

Gomina se asoyan oro yi lasiko abewo si oludari ajo naa, Oloye Olusegun Awolowo se sodo re nilu Ibadan.

Gomina eni to akowe ijoba ipinle Oyo Arabinrin Olubamiwo Adeosun soiju fun tenumo pe Ijoba Ipinle Oyo ti mu agbega ba ise agbe di aladanla nilana igbalode.

Gomina  salaye wi pe ijoba re ti se atunse opolopo ona lagbegbe igberiko lona ati mu igbe aye rorun fawon agbe.

Ninu oro re, oludari agba ajo ton ri si ipolongo oja kiko sowo sile okeere , NEPC, oloye olusegun awolowo pe fun ajosepo to dan moran pelu ajo naa fun ipese ise.

Oloye Awolowo tenumo pe ajo naa yoo se ise po pelu Ijoba Ipinle Oyo lati fi mu igba otun ba Oja Okerete to wa nilu Saki tii se enu aala ile yi fun anfaani awon eeyan Ipinle Oyo.

Adebisi/Salaudeen

Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti sodi mimo pe, awon iranse tawon yoo lo nibi eto idibo ti yoo wa lawon Ijoba Ibile, nipinle yii, kii se lati fi tako eto tawon oludibo ni lati fidibo. 

Nibi eto ibura fawon omo Igbimo tuntun fajo eleto idibo Ipinle Oyo, OYSIEC, ni Gomina ti soro yii di mimo, pelu alaye pe, Erongba Ajo OYSIEC naa ni lati seto idibo ti ko ni leja n bakan ninu, ti yoo si lo niroworese lawon ijoba ibile meteeta-lelogbon gege bofin ile yi se lakale.

O wa ro awon eeyan to n gbaradi saaju awon eto idibo odun 2023 lati fun rawon lomi suuru mu, kiwon si lafoju sun lori awon eyi to wanle lowo bayi.  Nigba to n soro loruko Ajo eleto idibo Ipinle Oyo, Alaga Ajo ohun, Ogbeni Isiaka Olagunju seleri pea won yoo sise awon gege bi ise igbimo tuntun tiwon yan fajo eleto idibo ipinle Oyo, naa OYSIEC niwon je igbimo elenu mejo.

Folakemi Wojuade