Yoruba

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ilẹ̀ yìí pè fún àdúrà sí ojútu sí àwọn ìsòro

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ilẹ̀ yíì Sẹ́nátọ̀ Ahmed Lawan, sopé orílẹ̀èdè Náijírìa nílò àdúrà kólè boorí àwọn ìpèníjà rẹ̀.

Sẹ́nátọ̀ Lawan sọ èyí nígbà tó ńgba àwọn asòfin tójẹ́ ọmọ lẹ́yìn Krístì lálejò.

Ẹgbẹ́ àwọn asòfin tó jẹ́ ọmọ lẹ́yìn Krítì ọ̀hún ní igbákejì adarí ilé Sẹ́nátọ̀ Ovie ọmọ-Agege àti akójanu ilé Sẹ́nátọ̀ Orji Uzor Kalu léwájú.

Adarí ilé wá rọ gbogbo ènìyàn láti kọ́kọ́ wá ojú Ọlọ́run kí ìdáhùn àdúrà lé wájú.

Ó fikun pé ojúse àwọn adarí ní láti máà fi ìgbàgbọ́gbo bèrè fún ìdásí Ọlọrun nínú ètò ìsèjọba àti fáwọn èèyèn àwùjọ.

Kẹmi Ogunkọla/Dada Oluwayẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *