Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti bèèrè fun yiyan ìgbìmọ̀ alábojútó fún ilé-ìwé tó ń rí sétò ẹ̀kọ́ alájẹsẹ́ku àtẹ̀kọ́ nípa ìdókóòwò, tó wà nílu Ìlọra níjọba ìbílẹ̀ Afijio nípinlẹ̀ yíì láti lè jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ isẹ́ ní pẹrẹ u.

Èyí ló wáyé níbamu pẹ̀lú àbá kan tóníse pẹ̀lú ìdí tófí se pàtàkì kíwọ́n sàmúlò òfin ọdún 2017, èyí tó sọ ilé-ìwé ọ̀hún di ilé-ẹ̀kọ́ gíga, eyi tasòfin tón sojú ẹkùn ìdìbò Afijio, ọ̀gbẹ́ni Seyi Adisa gbékawájú ilé.

Nígbà tó ń gbé àbá náà kalẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Adisa, sọpé òfin ọdún 2017 náà tó ró ilé-ẹ̀kọ́ náà lágbára láti máà sètò ẹ̀kọ́ Diploma, ni wọ́n ko sàmúlò rẹ̀ mọ́ látọdún tó ti pẹ́, èyí tí kò jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ isẹ́ ní pẹrẹ u.

Ọgbẹni Adisa kò sài fìrètí hàn pé, ki se pé ilé ẹ̀kọ́ náà yóò mágbega bá ẹ̀bùn táwọn ọ̀dọ́ ní nìkan bíkose pé yóò tun pèsè àyè sílẹ̀ fún ìgbanisísẹ́ tó bá bẹ̀rẹ̀ isẹ́.

Núnú ọ̀rọ̀ tìẹ, adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfinìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin, pàsẹ fún ìgbìmọ̀ tẹkótólé tón rí sọ́rọ̀ ìdókoowò àtètò alájẹsẹ́kù láti sèpàdé papọ̀ pẹ̀lú ilé-ìsẹ́ ọrọ̀ ajé àti ìdókoowò lọ́nà àti jíròrò lórí ipò tílé-ẹ̀kọ́ náà wa báyíì.

Ó wá rọ àwọn alásẹ láti yan àwọn ọ̀gá pẹ̀lú àwọn ìlànà ateele tíwọ́n yóò fi ma tukọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ náà.

Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *