Yoruba

Àgbáríjọpọ̀ Ẹgbẹ́ Òsìsẹ́ Fún Ìjọba Àpapọ̀ Ní Gbèdéke Ọ̀sẹ̀ Méjì Láti Yọ Àfikún Iye Owó Epo Pẹntirol Àti Epo Pẹntirol

Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ti setán láti bẹ̀rẹ̀ ìyansẹ́lódì jákèjádò orílẹ̀èdè yi láti ọjọ́ kejì dín lọ́gbọ̀n osù kẹsan, pẹ̀lú bí ìjọba àpapọ̀ se sí dúró lórí àfikún tó filé epo pẹntirol àti iná ọba.

Ìgbìmọ̀ alásẹ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ nílẹ̀ yí NLC, ti fi ọwọ́sí ìpinu èyí tí ìgbìmọ́ tón sisẹ́ lórí rẹ̀ , gbè, lẹ́yìn ìpàdé nílu Abuja.

Àwọn ẹgbẹ́ òsìsẹ́, NLC, àti èyí ta mọ̀ si TUC, sọ pé àwọn yo sisẹ́ papọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láti ri dájú pé, ìgbésẹ̀ wíwọ isẹ́ níran yi kẹ́sẹjárí.

Àrẹ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ NLC, ọ̀gbẹ́ni Ayuba Wabba sàlàyé pé àsìkò tí àfinkún dé bá àwọn ǹkan èlò wọ̀nyín ni kò bójumu pẹ̀lú bí ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19 kò se ti kogba wọlé àti wípé ìgbésẹ̀ yi kò ní jẹ́ kóríyá fún wọn láti sisẹ́ dunjun.

Àgbárójọpọ̀ òsìsẹ́ ni wọ́n ti wa fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ m€jì láti da iye owó epo pẹntirol àti ináọba síye tó wà tẹ́lẹ̀ tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìyansẹ́lódì

Kẹhinde/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *