Ilé ẹjọ́ magistrate nílu Àkúrẹ́ ti fi àwọn ẹni tí wan furasí pé, wọ́n jẹ́ jàndùkú olósèlú méje, tọ́wọ́tẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá pẹ̀lú àwọn on ìjà lọ́wọ́ níjọiba ìbílẹ̀ ose nípinlẹ̀ náà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Olokuta nílu Àkúrẹ́.

Àwọn ẹni tí wọ́n furasí méje yi, lọ́wọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ lọ́jọ́ àbámẹ́ta lójú ọ̀nà Ikarọ lásìkò tí wọ́n ńlọ lari pẹ̀lú mọ́tò tí wọ́n ya àwòrán ọ̀kan lára àwọn tó fẹ́ gbé àpótí ìbò dupò, Gómìnà.

Àmọ́ tí ẹni táwòrán rẹ̀ wà lára mọ̀tò sọ pé ounkọ mọ àwọn jàndùkú yi ri.

Adájọ́ Tọpẹ Aladejana wá ní kí àwọn èyàn wọ̀nyí wá logba ẹ̀wọ̀n títí táwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa yo fi parí ìwádi lórí ìsẹ̀lẹ̀ yí.

Adájọ àgbà tótúnjẹ́ alákoso fétò ìdájó nípinlẹ̀ Òndó, ọ̀gbẹ́ni Adekọla Ọlawoye sọpé, isẹ́ tó wà níwájú ìjọba ni láti dábòbò àwọn èyàn rẹ̀ ní pasẹ̀ lilo òfin tó yẹ, wọ́n ti sún ìgbẹ́jọ́ di ọjọ́ kejìlé lógún osù tónbọ̀ ọdún yi.

Adegbite/Afọnja   

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *