Yoruba

Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ yio gbàlejò ìdíje ẹ̀sẹ́ kíkàn àgbáyé

Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ni yio gbàlejò ìdíje ẹ̀sẹ́ kínkàn àgbáyé ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n osù yí.

Alága ìgbìmọ̀ tó ńse kòkárí ìdíje náà Ọlawale Okuniyi ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yí lásìkò tó kó ikọ̀ ìgbìmọ̀ rẹ̀ sòdí wá gbé bẹ́lìtì ìdíje náà wá han Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde lọ́fìsì rẹ̀ tó wà l’Ajodi nílu ìbàdàn.

Nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ lórí ìdíje náà, ọ̀gbẹ́ni Okuniyi ní ọdún 1963 ni ìlú ìbàdàn ti gbàlejò irú ìdíje yi gbẹ̀yìn ní pápá ìseré Liberty tíì se ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta sẹ́yìn.

Ó ní àkànse ọmọ ilẹ̀ yí Rilwan Adekọla tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Scopion tíì se ọmọbíbí ìlú ìbàdàn ni yio máà wáàko pẹ̀lú Lucas Matia Montesino ọmọ ilẹ̀ Argentina.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Gómìnà Makinde ẹnití akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Olubanwo Adeosun gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ni ìdàgbàsókè eré ìdárayá jẹ ìjọba lógún, ó wá jẹ́jẹ pé ìjọba tó wà lóde báyi yio sàtìlẹ́yìn tótọ́ fún ìdíje náà.

Gómìnà Makinde wá rọ abẹ̀sẹ́kùbí òjò náà láti jà fitafita láti léè gbé orúkọ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ àti ilẹ̀ Nàijírìa lékè nínú ìdíje tó ńbọ̀ lọ́nà náà.

Adebisi/Dada Yẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *