Yoruba

Ìjóba Àpapọ̀ Sàfíkún Àkókò Lórí Sísọ Nọ́mbá Ìdánimọ̀ Ọmọilẹ̀ Yí Mọ́ Ẹ̀rọ Ìbánisọ̀rọ̀ Papọ̀

Ìjọba àpapọ̀ ti sàfikún àsìkò ti àwọn ènìyàn ní láti so nọ́mbà ìdánimọ̀ ọmọ ilẹ̀ yí NIN, wọn mọ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn títí di ọjọ́ kankàndílógún osù kini ọdún 2021 fún oníruru ìsọ̀rí àwọn oníbarà ilé isẹ́ ìbáẹnisọ̀rọ̀.

Alákoso fọ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ nílẹ̀ yí, Ọ̀mọ̀wé Isa Pantami ẹnití ó sọ̀rọ̀ yí nílu Abuja sọ wípé ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ tó wà fún s;iso ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mọ́ nọ́mbà ìdánimọ̀ ọmọ ilẹ̀yí pọ̀ ló buwọ́lu àfikún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta yí.

Ọ̀mọ̀wé Pantami ni àjọ ńfẹnukò àwọn ọmọ ilẹ̀ yí sílẹ̀, NIMC, ti sàgbékalẹ̀ ìlànà láti ríì dájú wípé wọ́n dá àwọn ènìyàn lóhun ní ìbánu pẹ̀lú ìlànà àabò covid 19 ni paapajulọ lílò ìbòmú ti wọ́n pa ní dandan àti títakété síra ẹni.

Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *