Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde ti sèkìlọ̀ fáwọn èèyàn láti yàgò kúrò nídi àwọn ìgbésẹ̀ kan, èyí tó lè yọrísí fífi tìpá tikuuku yo yan kan kúrò nípò tàbí léwọn kúrò nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ìkìlọ̀ yíì ló wáyé níbamu pẹ̀lú dàrúdápọ tó wáyé láàrin àwọn àgbẹ̀ àtàwọn darandaran kan lágbègbè òkè-ògùn nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Gómìnà Makinde sàlàyé pé, ẹniyoowu tàbí ikọ̀ kankan tó ń bá gbèrò láti lọ kọlu àwọn èèyàn láti yàgò kúrò nídi isẹ́ bẹ́ẹ̀, torípé ìjọba òun kó tẹ́tí láti gbé ìgbésẹ̀ òfin tó bayẹ lórí ẹni tó bá ń gbìyànjú àti domi àlàfìa ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ rú.

Ó tẹnumọ́ pé, ìsèjọba òun ti pinu, láti dábobo ètò gbogbo èèyàn tón gbé nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, gẹ́gẹ́ bó se wá nínú àtúnse òfin ilẹ̀ yíì tọdún 1999.

wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *