Ọjọ́ burúkú èsù gbimi, lòníjẹ́ fún àwọn tón fi alùpùpù sisẹ́ se, lágbègbè Mọlete, Òkè-Àdó nílu ‘bàdàn, nígbàtí ọkọ̀ tón gbé epo diesel rọ́ lu arákùnrin kan tó sì sekupa.

Gẹ́gẹ́bí àwọn tọ́rọna sojúrẹ ti se lálàyé, ọkọ̀ àjàgbé ọ̀hún ló sọ ìjánu rẹ̀ nù tó sì kọ lu arákùnrin tón wa alùpùpù.

Awakọ̀ àjàgbé ọ̀hún ló ti sá àsálà fẹ́mi rẹ̀ ketẹ, tísẹ̀lẹ̀ náà wáyé, bóyá nítorí ìbẹ̀rùbojo káwọn èrò má gba ẹ̀san ẹni tó sekúpa lára fẹni.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria jábọ̀ pé, àwọn tón wa alùpùpù ni wọn kọ̀ láti jk kí ọlọ́pa gbé òkú arákùnrin yi lọ, káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ le sin lójú ọjọ́.

Agbẹnosọ fún ilé ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Olugbenga Fadeyi sọ pé ilésẹ́ náà tin sisẹ́ láti ri dájú pé àwọn ọmọ ìsọta ko da àláfìa ìlú rú nítorí ìsẹ́lẹ̀ náà.

Makinde/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *