Awon Gomina l’awon ipinle merindinlogoji nile yi ni won yio sepade papo lola lona ati wa ojutu sawon oniruuru ipenija to nkoju ile yi.

Egbe awon gomina nile yi NGF lo kede oro yi ninu atejade ti eniti o wa foro iroyin ati ipolongo won, Ogbeni Abdulrazaq-Bello Barkindo fi sita nilu Abuja.

Ogbeni Bello-Barkindo so wipe awon Gomina nibi ipade ori ero ayelujara ti yio bere ni aago meji osan yio jiroro lori ase ijoba, kewa, awon oro to nja rayinrayin ati ajakale arun Covid-19 to be sile fun igba keta.

O fikun wipe oludari agba fun egbe NGF, Ogbeni Asishana Okauru ni yio foro to won lati lori ibiti nkan de duro lori ase ijoba kewa nibi ipade ti won ti se pelu alakoso foro awon osise ati igbanisise, Omowe Chris Ngige.

Gegebi o se so, iyanselodi ti egbe awon osise ile ejo nile yi ati tawon osise ile igbimo asofin nile yi gunle naa wa lara ofin ti won yio gbe yewo.

Oluwayemisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *