Adari leka ti won ti nra nka ninu ile ise omo Ologun oju ofurufu, NAF, Ogagun Mohammed Yakubu ti so wipe awon omo ologun nilo owo o kete tan billion meji dollar lodoodun lati gbogunti igbesunmomi, ati awon ohun ti on fa bi eto aabo fi mehe nile yi.

O soro yi nibi ipade apero itagbangba eyiti igbimo teekoto ile igbimo asofin apapo keji lori oro aabo pe lori aba ofin sisatileyin fun, asunwon idawo fun ile ise omo ologun todun 2021 eyiti won fe fi wa ona miran ati wa owo fun awon omo ologun yato fun aba isuna won odoodun.

Ogagun Yakubu lasiko ti o nsalaye idi fun aba isuna so wipe awon to npe ohun elo awon omo ologun ni beere fun sisan owo won pe perepere saaju ipese won, to wa fikun wipe owo naa yio ni ninu dida awon omo ologun leko lori ilo awon irinse naa.

Adari leka ti won ti nra nkan naa tun so idi to fi sepataki lati ni aba isuna fun ile ise omo ologun ofurufu lati lee sise ti won gbe le won lowo doju amin.

Oluwayemisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *