Ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS, ti tẹnumọ́ ìpinu wọn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àjọ áàbò araẹni láàbò ìlú, NSCDC, láti wá ojútu sí ìsoro ọ̀rọ̀ ààbò àti àwọn ìwà ọ̀daràn nípinlẹ̀ yí.

Ọga àgbà ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́ arábìnrin Ngozi Ọnadẹkọ àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ọ̀gá àjọ DSS, arábìnrin Clara Onika ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò tí wọ́n lọ sàbẹ̀wò sí ọ̀gá àgbà àjọ NSCDC, ọ̀gbẹ́ni Micheal Adaralẹwa.

Ọga àgbà àjọ DSS, gbóríyìn fún àjọ NSCDC fún bí wọn se máà ńtètè gbé ìgbésẹ̀ nídi gbígbógunti ìwà ọ́daràn nípinlẹ̀ yi nípaapajulọ nídi dídàabòbò ọ̀pá epo, fífi ọmọ sòwò ẹrú àti àbójútó àwọn ilé isẹ́ aláàbo aládani.

Níti ẹ̀, ọ̀gá ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ yi sọ wípé kò sí ìkùnsínú kankan láàrin ilé isẹ́ ọlọ́pa àti àjọ NSCDC, tó wà jẹ́jẹ́ ifọwọsowọpọwọn nídi dídàabòbò ẹ̀mí òn dúkia àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nígbàtí ónfèsì, ọ̀gá àgbà àjọ NSCDC, nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Adaralẹwa mọrírì àwọn adarí àjọ elétò áàbò méjèèjì tó wà sèlérí àti múkí ìbásepọ̀ wọn máà tlsíwájú.

Bákanáà ló rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ láti máà sátìlẹ́yìn fún àjọ NSCDC, lórí fifi ọrọ tó wọn láti léè gbogunti ìwà ọ̀daràn nípinlẹ̀ yi.

Rasheedah Makinde/Ọlọlade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *