Ètò ìgbẹ́jọ asíwájú kan fún àwọn èyàn ilẹ̀ Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu ẹni tọ́wọ́ àwọn agbófinro tún tẹ̀ lana, ni wọ́n yo tlsíwájú láti ma gbọ́ ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrindinlọgbọn osù tón bọ̀.

Nígbàtí ètò ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀, nílé ẹjọ́ gíga nílu Abuja, agbẹnusọ fún ìjọba Shuaibu Labaran bẹ̀bẹ̀ pé kí iléẹjọ́ tètè gbọ́ ẹjọ́ náà, láti lè mú kí ìgbépọ̀ ọ̀hún yá ní kánkán.

Ilé ẹjọ́ tún pa lásẹpé, kí wán tó fojú Kanu ba ilé ẹjọ́ ni kí wọn kan sí agbẹjọ́ró rẹ̀, pẹ̀lú bóse wà láhamọ́ ọ̀dọ̀ àwọn DSS.

Adájọ́ Binta Nyako wa sun àsìkò ìgbẹ́jọ́ kúrò ní ogúnjọ́ osù kẹwa sí ọjọ́ kẹrindinlọgbọn àti ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n osù tónbọ̀.

Adájọ́ àgbà fún ilẹ yi tótúnse alákoso fétò ìdájọ́, ọ̀gbẹ́ni Abubakar Malami ẹni tóbá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, nísejú ọ̀gágba ilésẹ́ ọlọ́pa Usman Baba àti agbẹnusọ fún ikọ̀ DSS, ọ̀mọ̀wé Peter Afunnaya sàlàyé pé bí ọwọ́ tun se tẹ Kanu lóníse pẹ̀lú àjọsepọ̀ pẹ̀lú àjọ ẹ̀sọ́ alábo nílẹ̀ Nàijírìa àti àwọn ilésẹ́ ọlọ́pa lágbayé Interpol.

Adájọ́ àgbà fikun pé, ẹ̀sùn tíwọ́n fi kan, Kanu lóníse pẹ̀lú ìgbésùnmọ̀mí ìgbìyànjú láti dójú ìjọba dé, kíkọ́ on ìjà olóró jọ lái gbàsẹ tófimọ́ kíkó ẹgbẹ́ tí kò bófimú jọ.

Seyifunmi Ọlarinde/Ọlọlade Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *