Yoruba

Ìjọba Àpapọ̀ Yio Bẹ̀rẹ̀ Gbigba Abẹ́rẹ́ Àjẹsára Covid-19 Miràn

Àjọ tó ńrísí ọ̀rọ̀ ilé ìwòsàn aláàbọ́dé nílẹ̀ yí ti sọ wípé orílẹ̀ èdè yi yio gba abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 Pfizer-Biontech, Modena àti oxford Astrazenica láàrin osù yí sí osù kẹsan ọdún yí.

Adarí àgbà fún àjọ náà, Dókítà Pheza Shuab ẹnití ó sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nílu Abuja sọ wípé oníruru àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára yi ti ilẹ̀ America àti àjọ ìsọ̀kan ilẹ̀ adúláwọ̀ fi ta orílẹ̀ ede oyi lọ́rẹ ni yio de ni ìpele ìpele.

Nídi èyí, ìjọba àpapọ̀ ti ra irinsẹ́ U701 ultracode ibain tótó mokandín láàdọrin tí wọ́n fi ńse abẹ́rẹ́ àjẹsára lọ́jọ́ tí wọ́n si ti pín mktàdínlógójì sí gbogbo ìpínlẹ̀ mkrìndínlógójì àti olú ìlú yi ní ìgbáradì fún gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára covid-19 yi tó nílò láti tutu ni ìwọ̀n tí kò tó ogójì sí márùndínláàdọrun celcius.

Dókítà Shuab sọ wípé ilẹ̀ yí ti parí fífún àwọn ènìyàn ni abẹ́rẹ́ àjẹsára ìpele kini tó wà ní wọn tí bẹrẹ ìgbésẹ̀ lórí fífún àwọn ènìyàn lábẹ́rẹ́ ọ̀hún ní ìpele kejì.

Oluwayẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *