News Yoruba

Egbe NANS N Fe Ki ASUU Ati Ijoba Apapo Fenuko Lati Dena Iyanselodi

Aare Agbarijopo egbe awon akeko nile yi, NAN, Ogbeni Sunday Asefon, ti kesi ijoba apapo ati egbe awon osise nile eko giga varsity nile yi lati ni afenuko lori nkan ti won bere fun, ki won le yago fun eto iyanselodi ti yo sakoba fawon akeko.

Ninu atejade ti Are NAN fowosi lo ti rawo ebe si, ijoba ati egbe ASUU, ki won se on ti ko ni mu ifaseyin de ba eto eko awon akeko.

Ogbeni Asefon tokasi pe, lati asiko ti ijoba awarawa ti bere lodun 1999, asiko ti iyanselodi fi ti waye tile ni odun marun, ti ko si ye ki egbe ASUU tun bere iyanselodi miiran leyin eyi to waye lodun to koja.

 NET/ Afonja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *