News Yoruba

Onimo Nipa Eto Eko Pe Fun Gbigba Alaafia Laaye Pelu Bile Agbaye Se N Sami Ayajo Ojo Alaafia

Ni bayi tile agbaye n samin ayajo ojo alaafia onimo nipa eto eko kan, to tun je oloselu, omowo Fola Akinosun ti tenumo Pataki kawon omo ileyi maa gba alaafia laaye lai nani eya, esin tabi egbe oselu ti koo wa wa.

Omowe Akinosun ti ise ekan egbe oselu All Progressive Congress, APC, nipinle Oyo soro imoran naa lasiko iforowero pelu awon akoroyin Radio Nigeria.

Nigba to yannana Pataki awujo talafia wa gegebi isokan, ife ati idagbasoke, Omowe Akinosun salaye pe idagbasoke Kankan kole way lawujo ti wahala, aifayabale ogun ati aiseto aabo bawa.

Omowe Akinosun wa sekilo tako, eleyameya, to fi mo wahala elesinjesin to maa n fa aisi isokan lorileede pelu alaye pe orileede yi sile bo ninu awon ipenija to n koju taba duro gegebi eyokan soso;

Ko sai ro awon oloselu lati jina si oselu etanu ati lati ri daju pw idajo ododo wa fun gbogbo eeyan.

Kehinde/Olaopa

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *