Àwọn akópa níbi ètò ìlanilọ́yẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́ àláàfìa tí àjọ áàbò araẹni làbò ìlú ìpínlẹ̀ Ọsun gbé kalẹ̀ láti sàmìn àyájọ́ àláàfìa lágbayé ti sàpèjúwe ìdájọ́ òdodo, ìlànà tótọ́ àti ìfikùnlukùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá kùtẹ̀lẹ̀ fún ìdàgbàsókè àwùjọ tálafìa wa.

Àwọn akópa lẹ̀yìn tatirí àwọn adarí ìlú, àwọn olórí agbègbè àwọn ẹ̀sọ́ aláàbo àwọn olórí ẹ̀sìn, àwọn ajàfẹ́tọ ọmọnìyàn àtàwọn tówà lẹ́ka ẹ̀sọ́ ẹ̀kọ́ fẹnukò lórí pàtàkì àláàfìa fún ìdàgbàsókè ìlú.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀gá àgbà àjọ ààbò araẹni láàbò ìlú nípinlẹ̀ Ọsun, ọ̀gbẹ́ni Emmanuẹl Ocheja ni ohun nígbàgbọ́ pé àwọn ìpèníjà tó n kojú ètò àbò nílẹ̀ Nàijírìa ni kóni pé rokun ìgbègbé pẹ̀lú ríró àwọn ẹni tọ́rọkàn lórí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́ tàláfìa láti máà jẹ́ olódodo pẹ̀lú dídáró déèdé.

Ẹwẹ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ọba alayé kan iyẹn owaloko tí Iloko Ijesa, ọba Hakeem Ogungbangbe dirẹbe si àwọn adarí, ní gbogbo ẹ̀ka, papajulọ àwọn tó n wá ipò òsèlú láti yàgò fún dídá rúgúdù sílẹ̀ pẹ̀lú ìse wọn.

Ọlarinde/Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *