News Yoruba

Ọwọn Gógó Owó Ilé Ìwé Ti Fa Kíkó Kúrò Àwọn Akẹ́kọ Nílé Ẹ̀kọ́ Aládani Ìpínlẹ̀ Èkó Látọwọ́ Àwọn Òbí Àtalágbátọ́

Àwọn òbí àti alágbàtọ́ kan ti wọ́n ko lágbára àti san owó ilé ẹ̀kọ́ tó di ọ̀wọ́ngógó ti bẹ̀rẹ̀ síní mú àwọn ọmọ wọn kúrò láwọn ilé ẹ̀kọ́ aládani tón bẹ nípinlẹ̀ Èkó.

Ìròyìn fidiẹ múlẹ̀ pé àwọn òbí tọ́rọ̀ kan àti alágbàtọ́ ni wọ́n ńkó àwọn ọmọ wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìjọba.

Àwọn akọ̀ròyìn fidiẹ múlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ ọ̀hún kòrí bí tàtẹ̀yìnwá táwọn èyàn máà ń kí ìwọlé padà akẹ́kọ tìlù tìfọn, àwọn ilé ìwé kọ́ọ̀kan tí wọ́n dé, sàfihàn pé ǹkan kò fi bẹ sẹnu re.

Láwọn ilé ìwé kan, wọ́n ní níseni yàrá ìkàwé dá paropáro pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ se kọ̀ láti padà sílé ẹ̀kọ́.

Ọkan lára olùdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ tọ́rọkàn lágbègbè Ìfàkọ̀-Ìjàyè, nígbà tón bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, lórí bí ilé ẹ́kọ́ náà se dami sàlàyé pé àwọn òbí kan lára àwọn òbí tó lọ́mọ nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ti fi jo ìgbìmọ̀ alásẹ ilé ẹ̀kọ́ náà láti pe àwọn ọmọ àwọn kòní le padà wọlé sílé ẹ̀kọ́ náà mọ.

Òsìsẹ́ kan láti ilé isẹ́ ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ Èkó, sàlàyé pé àwọn tí wọ́n wọlé sílé ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àti girama tó jẹ́ tìjọba ló ti lọ sókè láti bí osù kan sẹ́yìn.  

Ọlarinde/Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *