News Yoruba

Ìjọba Àpapọ̀ Yóò Kojú Oro Sáwọn Tó Bá Ń Ba Dúkia Ilé Isẹ́ Panápaná Jẹ́

Alákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla ti sọpé ìjọba àpapọ̀ yóò sisẹ́ lórí àwọn ọ̀daràn tó n sèkọlù sí àwọn òsìsẹ́ panápaná àti àwọn dúkia ilé isẹ́ náà jákèjádò ilẹ̀ Nàijírìa.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla yọjú ọ̀rọ̀ náà síta lásìkò tón sísọ lójú ọkọ̀ panápaná olówó iyebíye tuntun tíjọba àpapọ̀ kó lọ sílé isẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Taraba nílu Jalingo.

Ó sàlàyé pé, ìjọba àpapọ̀ ní kòní fàyè gba àwọn ọ̀daràn tón man sèkọlù ohun bíba dúkia àjọ náà tó wà fún dídáàbò bo ẹ̀mí àti dukia àwọn aráàlu lọ́wọ́ ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná jẹ́mọ́.

Alákoso ọ̀hún sàfikún àlàyé rẹ̀ pé, èrè ìdí kíkó ọkọ̀ panápaná ìgbàlódé ohun lọ sípinlẹ̀ Taraba lójẹ́ èróngbà ìsèjọba Arẹ Buhari lórí àtúntò ilé isẹ́ panápaná pẹ̀lú ìfọkànsìn sí isẹ́ ìlú.

Sáàjú ni alámojútó ilé isẹ́ panápaná ìjọba àpapọ̀, ọ̀mọ̀wé Imam Ibrahim ti sàlàyé pé àwọn ọkọ̀ panápaná tuntun ti wọn kó wá sí ìpínlẹ̀ Taraba lójẹ́ àfikún isẹ́ tìjọba ìpínlẹ̀ náà tise.

Ọlarinde/Ọlaọpa

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *