Yoruba

Àbẹ̀wò Ìbánikedùn Ikọ̀ Alábútó Ilé Isẹ́ Radio Nigeria Ìbàdàn

Ikọ̀ alábójútó ilé-isẹ́ Radio Nigeria àpapọ̀ ilẹ̀ wa, lẹ́kùn ìbàdàn, ti se ìbánikẹ́dùn pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ ìbàdàn àti ìpìnlẹ̀ ọ̀yọ́ lápapọ̀ lórí ìpopòdà Olúbàdàn tilẹ̀ ìbàdàn Ọba Saliu Adetunji, tó darapọ̀  máwọn babanla rẹ̀ lána òde yíì.

Ètò ìbánikẹ́dùn náà niwọ́n se lọ sáàfin olúbàdàn tó wà ládugbò pópó Yemọja tíkò alabojutonáà, èyí tí olùdarí àgbà pátápátá fúnlesẹ́ náà lẹ́kùn ìbàdàn arábinrin Bolatito Joseph léwájú fún.

Arábìnrin Joseph sàpèjúwe ọba Adetunji gẹ́gẹ́ bí ọba alayé tókó èèyàn mọ́ra, tó lo gbogbo ìgbésíayé rẹ̀ fún ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn.

Bẹ́ẹ̀ ló si rọ gbogbo àwọn ẹbí ọba alayé náà láti máà yẹsẹ kúrò lórí àwọn isẹ́ rere tọ́ba Adetunji fisílẹ̀.

Folakemi Wojuade/Oluwakayode Banjọ

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *