Yoruba

Gomina ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti salaye igbiyanju eto isakoso ijoba re lori ati koju ipenija eto aabo nipinle naa.

Gomina Makinde se adayanri oro yi lasiko to n gbalejo asoju awon logaloga ileese olodun to lo fun eto idanileko eleekerinlelogoji ile eko oloogun to wa ni Jaji labe akoso asaaju iko naa, eni tii se ogagun ofurufun Air Vice Marshal Ebenezer Alade.

Nigba to n soro lori akori idanileko won naa ti se mimu idagbasoke ba eto aabo nipase igbiyanju nidi eto amulundun ati oro aje, Gomina Makinde salaye wi pe ijoba re ti ro awon odo lagbara, pelu kikowon kuro loju popo leyi to ti mu ki iwa odaran dinku nipinle Oyo, bee lo tun soo di mimo pe ijoba re, ti pese ina sawon oju popo leyi to mu ki igboro maa wa ni imole lalaale.

Saaju ni oludari iko naa, Air Vice Marshal Ebenezer Alade ti soo di mimo pe won ti yan ipinle Oyo, ninu awon ipinle mejo lorileede yi fun ibi ti abewo lori idanilejo naa yii ti maa waye.

Ayodele Olaopa 

News Yoruba

Gomina Seyi Makinde tipinle Oyo ti beere fun atileyin ile ise omo ologun ile yi lawon enu aala Ipinle Oyo lati lee jeki Alafia ati aabo fese rinle.

Gomina Makinde soro yi lasikko ti olori awon omo ologun ile yi, Ogagun Farouq Yahaya sabewo si lara abewo enu ise re si ekun keji ile ise omoologun to wa ni Bareki Odogbo l’Ojoo nilu Ibadan.

Niigbeti o nfidi re mule pe looto ni gbun-gbun-gbun nwa laarin awon eeya ile yi, Gomina Makinde gboriyin fun ile ise omo ologun fun isapa re nidi gbigbogunti awon ipenija oro aabo tile yi nkoju.

Gomina wa jeje wipe ijoba ti oun nle waju re yio ma tesiwaju lati ko ipa tire nidi gbigbaruku ti ile ise omo ologun lati lee daabobo ile yi.

Saaju ni olori awon omo ologun ile yi, ogagun Farouq Yahaya ti mo riri Gomina Makinde fun iranlowo re fun ekun keji ile ise omo ologun ile yi.

Makinde/Owonikoko

News Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde ti soo di mimo wi pe ijoba re ti n sapa lati fi ri daju pe idagbasoke to nitumo jeyo nidi igbiyanju ati wagbo dekun fun eto aabo to mehe nipinle Oyo.

O sipaya oro yi lasiko ti awon omo ile igbimo asofin ile yi ti won n soju ipinle Oyo ti won je omo egbe oselu PDP lo baa lalejo loofisi re nilu Ibadan.

Gomina Makinde salaye wipe ijoba re ko kaare lori amigboro eto aabo.

Gomina makinde ro awon omo ile asofin naa pe ki won maa se ipade pelu awon eeyan ekun idibo won loorekoore, ki adiinku lee ba eru to wa lorun ijoba ipinle.

Saaju ni, omo ile igbimo asofin agba to n soju ekun idibo Guusu Ipinle Oyo, Dokita Kola balogun, to soro loruko awon yoku ti kan saara si Gomina Makinde fun ilosiwaju lolokan o jokan to n mu ba ipinle Oyo.

Senator Balogun tun seleri wipe awon omo egbe oselu PDP to w anile asofin ile yi ko ni kaare ninu atileyin fun ijoba to wa lode nipinle Oyo.

Adebisi/Salawudeen

Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde tip e awon oloye tuntun egbe oselu PDP fekun guusu iwoorun ile yi nija pe ki won rii daju pe ajosepo to danmoran wa laarin awon omo egbe to n fi apa janu.

O soro yi lasiko eto ibura fun awon oloye tuntun naa nile egbe oselu PDP fekun guusu iwoorun ile yi labe akoso Alaga egbe naa nile yi, iyen Ambassador Taofeek Arapaja, eto ohun lo waye nile ijoba, nilu Ibadan .

Gomina Makinde salaye tenumo idi to fi ye kawon omo egbe gbagbe or ana, ki won gbajumobi egbe won yoo se jawe olubori lasiko eto idibo gbogbo ti yoo waye lojo iwaju.

Nigba to n soro, Alaga tuntun fekun guusu iwo oorun ile yi ninu egbe oselu PDP, Ambassador Taofeek Arapaja tenumo atunto ati idagbasoke egbe naa pelu igbayegbadun gbogbo omo egbe nibamu pelu ofin egbe.

Saaju ninu oro ikini kaabo re adele alaga fekun guusu iwo oorun ile yi ninu egbe oselu PDP Ogbeni Dayo Ogungbenro salaye idunu re wi pe egbe oselu PDP n fojoojumo gbile si pelu okan o jokan ipenija to tun n koju won.

Salaudeen

Yoruba

Ijoba Ipinle Oyo ti pese owo iwuri oju ese fawon iko elere idaraya ton soju ipinle Oyo ti won ti gba ami eye nibi idije ere idaraya ile yi ton lo lowo nipinle edo.

Nigba ton fun won ni owo naa nibudo ti won pago si nile eko giga Fasiti Benin Alaga Ajo Elere Idaraya Ipinle Oyo, Oloye  Gbenga Adewusi salye wi pe igbese yi lo le je koriya fawon elere idaraya akegbe won ti won jo n soju Ipinle  Oyo  lati ri daju pea won wa gba ami eye.

 Oloye adewusi salaye wi pe igbese ebun owo fawon elere idaraya yi lo je Igbiyanju Gomina Seyi Makinde lati fi gbe won laruge

Oloye Adewusi soo do mimo pe ileese oun lo fun won ni egberun marun, nigba to oga agba ajo elere idaraya Ipinle Oyo Ogbeni Gbenga Makinde naa fi egberun marun kun ogun egberun naira tijoba Ipinle Oyo so pe ki won maa fun elere idaraya to ba gba ami goolu.

 Awon elere idaraya meji to ti gba ami goolu lo tewo gba egberun lona ogbon enikookan, nigba tawon merin to gba ami wura gba egberun mewa naira enikookan, ti awon mejidinlogun to gba ami fadaka si gba egberun marun naira  enikookan .

Salaudeen

Yoruba

Gomina Ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde so pe gbogbo eto ti isejoba re la kale lo tin lo lowo lati mu ki papako ofurufu ilu ‘Badan di eyi ti gbogbo eeyan lekun yi joma lo.

O siso loju oro yi, lasiko ti ogaagba ileese Ologun Ofurufu, Air Vice Marshal Olaonipekunn Makinde se abewo ekuse n beun si loffise Gomina, Secretariat Ibadan.

Gomina makinde tokasi pe isejoba re yo mu ki agbega de baa ise ohun elo amayederun, kitesiwaju le deba eto oro aje Ipinle Oyo.

Gomina se lalaye pe isejoba re ti setan lati fee ibi ti baalu yo ma ba si, ko gba oko ofurufu to tobi, ti yo mu ko di lilo biti papako ofurufu ilu Eko.

Saaju ni Ogagun Makinde ti fi emi imore han si Gomina, pelubo ti n se atilehin fun ileese ologun ofurufu, to si wa fowo idaniloju soya pe ileese ohun yio tesiwaju lati sise fi ese abo to munadoko mule lori emi at dukia araalu.

Afonja

Yoruba

Gomina ipinle oyo, onimo ero seyi makinde ti so pe isejoba re, yo tesiwaju lati ma fi awon liana lele ti yo mu keto oro aje gboro si nipinle yi.

O soro yi lasiko, ton forowero pelu awon asaju ninu oja ati pelu awon egbe onise owo yika ipinle oyo, eyito waye nilijoba to wa ni agodi nilu Ibadan.

Otenumo pe isejoba re, yo saa gbogbo ipa lati mu ki oro aje awon ontaja ru gogosi, tigbe aye yo si fi rorun si fun mutumuwa .

Lori rogbodiyan to w anile lori yiyan asju legbe awon oloja gomina yan pe ohun o se agbekale  igbimo ti yio sise yanju gbogbo gbungbungbun na.

Saaju, oludari lekun iwo orun guusu fun egbe awon ountaja  nile naijiria arabirin odunayo danjuma  ro gomina lati dasi, ko si tun yanju  ikusinu to wa nidi yiyan asiwaju larin ountaja lokunrin lobirin  ni ipinle yi

Adebisi/Afonja

Yoruba

Ni ipalemo fun eko idibo si awon ijoba ibile nipinle Oyo, Gomina Seyi Makinde ti sefilole igbimo ti yio sagbeyewo bi awon adale alaga ti se sise kun oju osuwon si ni awon ijoba ibile meteetalegbon.

Ifilole igbimo naa to waye nile ijoba to wa ni Agodi nilu Ibadan.

Gomina Makinde ni igbimo naa gbodo fesi abajade won sita leyin ti won ba ti gbe ise si awon adele alaga naa wo.

Nigbati o nba awon oniroyin soro, Alaga Igbimo tuntun naa,  Senato Monsurat Sunmonu jeje wipe igbimo naa yio sise ti igbimo alase gbe le won lowo bii ise.

Awon igbimo eleni marun ohun ni won ni ose merin lati fi sise.

    Adebisi/Dada