Yoruba

Gomina Makinde Beere Fun Ajosepo Awon Omo Egbe Oselu PDP

Gomina Ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde tip e awon oloye tuntun egbe oselu PDP fekun guusu iwoorun ile yi nija pe ki won rii daju pe ajosepo to danmoran wa laarin awon omo egbe to n fi apa janu.

O soro yi lasiko eto ibura fun awon oloye tuntun naa nile egbe oselu PDP fekun guusu iwoorun ile yi labe akoso Alaga egbe naa nile yi, iyen Ambassador Taofeek Arapaja, eto ohun lo waye nile ijoba, nilu Ibadan .

Gomina Makinde salaye tenumo idi to fi ye kawon omo egbe gbagbe or ana, ki won gbajumobi egbe won yoo se jawe olubori lasiko eto idibo gbogbo ti yoo waye lojo iwaju.

Nigba to n soro, Alaga tuntun fekun guusu iwo oorun ile yi ninu egbe oselu PDP, Ambassador Taofeek Arapaja tenumo atunto ati idagbasoke egbe naa pelu igbayegbadun gbogbo omo egbe nibamu pelu ofin egbe.

Saaju ninu oro ikini kaabo re adele alaga fekun guusu iwo oorun ile yi ninu egbe oselu PDP Ogbeni Dayo Ogungbenro salaye idunu re wi pe egbe oselu PDP n fojoojumo gbile si pelu okan o jokan ipenija to tun n koju won.

Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *