Yoruba

Awon osise nileese oko ojurin nile yi NRC ti bere iyanselodi ikilo olojo meta leyi to ti mu eto irinna oju irin jakejado ile yi pakaso.

Awon osise eka naa lo ti seleri wi pea won yoo pagidina igbokegbodo oko ojurin jakejado ile yi to fi mo eto irinna oju irin to gbojugboya lati ilu Ibadan silu Eko, ati Abuja si Kaduna pelu Warri si Itakpe.

Lose to koja ni egbe awon osise oko ojurin labe akoso egbe osise, ile yi NLC dunkooko pea won yoo funle iyanselodi ikilo olopa meta lati fi beere fun eto igbayegbadun won.

Ni bai na, nidi ati ma le je kiyanselodi naa o waye, alakoso eto irinna nile yi, Ogbeni Rotimi Amaechi se ipade pelu awon igbimo egbe na nilu Eko, sugbon ipade naa ko so eso rere.

Ayodele Olaopa

News Yoruba

Aare Agbarijopo egbe awon akeko nile yi, NAN, Ogbeni Sunday Asefon, ti kesi ijoba apapo ati egbe awon osise nile eko giga varsity nile yi lati ni afenuko lori nkan ti won bere fun, ki won le yago fun eto iyanselodi ti yo sakoba fawon akeko.

Ninu atejade ti Are NAN fowosi lo ti rawo ebe si, ijoba ati egbe ASUU, ki won se on ti ko ni mu ifaseyin de ba eto eko awon akeko.

Ogbeni Asefon tokasi pe, lati asiko ti ijoba awarawa ti bere lodun 1999, asiko ti iyanselodi fi ti waye tile ni odun marun, ti ko si ye ki egbe ASUU tun bere iyanselodi miiran leyin eyi to waye lodun to koja.

 NET/ Afonja

News Yoruba

Egbe awon Dokita, to ngba imo kun imo, lati di akosemose, sope awon yoo gunle iyanselodi alainigbedeke, lojobo tijoba apapo baa kuna lati dahun si ibere won.

Ninu atejade eyi ti won fisita leyin ipade egbe nee nilu Abuja, Aare egbe ohun, Dokitia Uyilawa Okhauaihesuyi ati akowe agba, Dokita Jerry Isogun fowosi bere fun sisan ajeele owo osu oje ese, fawon osise to fimo owo osu keta kosu yi to pari.

Net/Idogbe

News Yoruba

Gbogbo ǹkan ló pakasọ lówurọ òní nílé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ nítorí bágbe àwọn òsìsẹ́ ẹ̀ka ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípinlẹ̀ yíì, se gba ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sílé ìgbìmọ̀ asòfin náà tìpa.

Ìgbésẹ̀ yíì ló wáyé níbamu pelu olùfẹ̀hóhàn tíwọ́n gùnlẹ̀ èyí tíwọ́n fin bèèrè fómìnira ètò ìsúná fáwọn asòfin ọ̀hún.

Oníròyìn ilé-isẹ́ Radio Nigeria, tó wà níbùdó ilé ìgbìmọ̀ asòfin ọ̀hún, jábọ̀ pé, lọ́pọ̀ yanturu làwọn ẹgbẹ́ náà tújàde, lẹ́nu olùfẹ̀hóhàn wọn ọ̀hún, tíwọ́n sì gbé ilẹ̀kùn tìpa.

Àwọn olùfẹ̀hóhàn náà, tíwọ́n wọ asọ aláwọ̀ pupa pelu onírunru àkọlé lọ́wọ́, bi ótitó gẹ́ẹ̀, ẹ fún ẹ̀ka asòfin lómìnira ètò ìsúná rẹ̀.

Alága ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ nílé ìgbìmọ̀ asòfin ilẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Yẹmi Alade, sàlàyé pé, ẹgbẹ́ náà gùnlẹ̀ ìyansẹ́lódì aláinigbèdeke láti fi bèèrè sísàmúlò òfin káwọn èyí táàrẹ fọwọ́sí lọ́dún tókọjá.

Kò sài fikun pé, bílẹ̀ Nàijírìa yóò bá fojú gáanní ìsèjọba àwarawa tóòtọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ fún gbogbo ẹ̀ka ìjọba lómìnira ètò ìsúná rẹ̀.

Ọgbẹni Alade sọ pé, ìyansẹ́lodì ọ̀hún yóò tẹ̀síwájú títí dìgbà tíjọba bá ń dáhun sí ìbeere àwọn.

Bákanà, lọmọ sorí nílé asòfin ìpínlẹ̀ Ògùn, níbi tí wọ́n tigbé ilẹ̀kùn ilé asofin tiwọn náà tìpa, tẹ́gbẹ́ náà sì pè fún ìyansẹ́lódì gbogbogbò fáwọn osise ilẹ̀ yíì.

Ogunyẹmi/Wojuade   

Yoruba

Àwọn akẹ́kọ ilé ẹ̀kọ́ gíga nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ lówurọ̀ òní péjọ sílé isẹ́ ìjọba àpapọ̀ láti fẹ̀húnúhàn lórí bí ìyansẹ́lódì ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ASUU, tise múkí wọn wà nílé fúngbà pípẹ́.

Àwọn akẹ́kọ náà tí wọ́n gbé àkọlé oníruru lọ́wọ́ ni wọ́n dí ẹnu ìloro ilé isẹ́ ọ̀ún.

Akọ̀ròyìn ilé isẹ́ Radio Nigeria jabọ̀ pé, òpópónà tó so agbègbè Custom mọ́ Gate n’ílu Ìbàdàn ni wọ́n gbégi dí.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu wò, àarẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ ẹ̀ka ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga tìlú ìbàdàn, ọ̀gbẹ́ni Olusẹgun Akẹju ní ìwọ́de tí wọ́n se ni ò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òsèlú kankan tàbí ti ẹgbẹ́ ASUU nínú rárá.

Rotimi Famakin/Yẹmisi Dada

News

Awon osise eleto ilera nipinle Oyo ti darapo mo awon akegbe won lati gunle iyanselodi ti egbe agbarijo awon osise Eleto Ilera nile yi JOHESU pase re.

Iyanselodi ohun lo bere ni aago mejila oganjo oru loni to si tii nmuki nkan pakaso leka eto ilera kaakiri ile yi.

Ninu iforowero pelu akoroyin ile ise Radio Nigeria, Alaga Egbe JOHESU eka tile iwosan ekose isegun, UCH, Ogbeni Adeolu Alli ni iyanselodi naa waye leyin ti won ti se opolopo suuru pelu Ijoba apapa fun bi odun meta

Ogbeni Ali wa gba awon omo egbe lamonran lati tele awon ase ti egbe fi sita titi ti won yio fi jare ninu sita.

Ibomor/Dada