Yoruba

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọyọ gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ sọpé, òun kòní yíì ìpinu òhun padà láti gbé àwọn ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ aládani tí o kójú òsùwọ̀n tàbí àwọn tójẹ́ gbígbékalẹ̀ láibofinmu tìpa.

Alága àjọ Subẹb nípinlẹ̀ Ọyọ, ọ̀mọ̀wé Nureni Adeniran sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ nígbà tó ńbá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nílu Ìbàdàn.

Ó sàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà sepàtàkì nítorí báwọn ilé-ẹ̀kọ́ náà se ńkùnà nídi ìlànà atẹle, bí ìforúkọsílẹ̀ lọ́nà tóóyẹ, ìpèsè àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ tó yẹ àti àyíká tódara f;etò ẹ̀kọ́.

Ọmọwe Adenira wá sọ́di mímọ̀ pé, ìgbìmọ̀ pàtàkì kan yóò jẹ gbígbé kalẹ̀ láti sisẹ́ tọ́ọ̀ ìgbésẹ̀ títí àwọn ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ aládani tí ó kójú- òsùwọ̀n náà páà pẹ̀lú àfikún pé, ìgbìmọ̀ náà yóò sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àjọ Subeb àti ilésẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Sciẹnce àti tìmọ̀ ẹ̀rọ nípinlẹ̀ Ọyọ.

Kemi Ogunkọla/Iyabo Adebisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *