Yoruba

Adarí ẹ̀sìn dába ọ̀nà láti mú kétò ìdájọ́ máà yá si

Ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí ìbásepọ̀ tó múnádoko kówà láàrin gbogbo ẹ̀ka ìjọba, ni ójẹ́ kókó ọ̀rọ̀ tó jẹyọ níbi síse ayẹyẹ ọdọdún àwọn amòfin fọ́dún 2019/2020.

Nínú ètò ìdánilẹ́kọ èyí tí ọ̀jọ̀gbọ́n Wọle Abbas tó wà láti ẹ̀ka tí wọn tin kọ́ nípa ìmọ̀ Arabic, nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ìbàdàn, ó takasi wípé kí ètò ìdájọ́ lè rẹ́sẹ̀ walẹ̀, óyẹ kí àwọn tón fi ẹsẹ̀ òfin múlẹ̀ se àtìlẹ́yìn fún ẹ̀ka ọ̀hún.

Ó tún gba àwọn amòfin níyànjú láti sisẹ́ wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run ọba.

Bishọpu àgbà níjọ Àgùdà ẹniọ̀wọ̀ Joseph Akinfẹnwa ti bèrè fún yíyan àwọn adájọ́ si nílẹ̀ yí, kó lè mú kétò ìdájọ́ ma yá si nílẹ̀ Nàijírìa.

Igbákejì Gómìnà nípinlẹ̀ Ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Rauf Ọlaniyan ti sèlérí pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ yo pese gbogbo ohun tí ẹ̀ka ìdájọ́ nílò láti lè dá dúró.

Kẹmi Ogunkọla/Adebisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *