Yoruba

Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ilẹ̀ yí ńgbèrò láti yansẹ́lódì

Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ilẹ̀ yí ti fi ìpinnu hàn láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ fún ìyansẹ́lódì tó ńgbèrò káakiri ilẹ̀ yí lọ́jọ́ kẹrìndínlógún osù yí tí ìjọba bá kùnà láti mú àtúnse tó yẹ bá ọ̀rọ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náirà owó òsìsẹ́ tuntun.

Nígbà tó ńsọ̀rọ̀ nílu Èkó, àarẹ ẹgbẹ́ TUC, Quadri Ọlalẹyẹ wòye pé fífalẹ̀ sísan owó osù náà ló dá lórí bí àwọn tó ńsojú ìjọba àpapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ owó osù tuntun náà se ńsọ ohun tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ fún àarẹ Buhari lórí owó osù tuntun náà.

Kẹmi Ogunkọla/Akintunde  

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *