Yoruba

Ilese Ologun Doola Awon Akeko Mefa Lowo Ajinigbe

Iko awon oloogun ile yi ti won pe ni Operation Thunder Strike ti doola awon akeko mefa ti won je akeko  ile iwe Government Day to wa ni Gwawada, ipinle Kaduna, eleyi tawon kan jinni gbe lasiko ti won n lo sileewe laaro ana.

Igbakeji oludari eka agbenuso owo keji ileese oloogun ile yi to wa nile Kaduna, Colonel Ezindu Idimah li foju oro yi lele fawon oniroyin nilu Kaduna.

Colonel Idimah soo di mimo pe won doola okunrin meta ti won je omo eyin oko, ti won si tu awon afurasi merin ka nibi ti won farasinko si.

Colonel Idimah salaye wi pe, awon agbebon naa ni won sina ibon bole nigba ti won kefin awon oloogun sugbon tawon oloogun ile yi fagba han won.

O salaye pe gbogbo awon akeko ti won jiko naa ni won gba pada lalaafia ti won si ti pada sodo ebi won.

Oluwayemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *