Yoruba

Gómìnà Makinde ní òun ò ti si ilé ìwé padà

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti ní ojú ò kán òun láti sílẹ̀ kùn àwọn ilé ìwé padà àyàfi tí òun bá gbọ́ ìmọ̀ràn láti ẹnu àwọn akọ́sẹmọ́sẹ́.

Ó sọ̀rọ̀ yi níbi àkànse ìjóko ilí ìgbìmọ̀ asòfin láti sàmì ayẹyẹ ọdún kan tí wọ́n fi ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ yi elẹ́kẹsan lọ́lẹ̀.

Ó rọ gbogbo àwọn tí wọ́n ńharagaga kí ìjọba sí àwọn ilé ìwé padà àti kíka òfin tó de ìpéjọpọ̀ ẹ̀sìn àti ayẹyẹ láti túbọ̀ se súùrù.

Gómìnà ní irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yíò gbé lẹyin ti wọ́n báti sàgbéyẹ̀wò ìwádi tí àwọn akọ́sẹmọ́sẹ́ ńse lọ́wọ́.

Oluwayemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *