Ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ kejì ti késí olùsírò owó àgbà nílẹ̀ yí, Ahmed Idris láti wá se ìsirò gbogbo owó tí àwọn ènìyàn dá fún ìjọba àpapọ̀, àjọ tó ńgbogunti àjàkálẹ̀ àrùn nílẹ̀ yí, NDCD, àti àwọn ilé isẹ́ ìjọba tọ́rs kàn láti fi gbogunti àjàkálẹ̀ àrùn covid-19.

Alága ìgbìmọ̀ tẹ́ẹ̀kótó ilé lórí àwọn àsùnwọ̀n gbogbogbò, Oluwọle Oke ló pàsẹ ọ̀rọ̀ yí níbi ìpàdé tí ìgbìmọ̀ náà pe láti mọ̀ nípàtó iye owó ará ìlú tí ìjọba ti ná láti fi gbógunti àjàkálẹ̀ àrùn ọ̀ún.

Ìgbìmọ̀ náà ti ní bèèrè lọ̀wọ̀ olùsírò owó àgbà nílẹ̀ yí láti sọ iye owó tí ìjọba àpapọ̀tí kó sílẹ̀ fún àwọn ìpínlẹ̀, àjọ NDCD, ilé isẹ́ ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ìlera àti àwọn lájọlájọ ìjọba tí wọ́n léwájú nídi bgíbgógunti àrùn yi.

Wọ́n tí tún ti ní kí olùsírò owó àgbà sọ iye owó tí wọ́n ti fún ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ lórí covid-19 kí wọ́n si bí owó tó lé ní bíllìọ̀nù méjìlélógún ti àwọn ará ìlú ti da fún ìjọba. ìgbìmọ̀ ọun wá ní wọn fún wọ́n de ìgbà ìjóko ìgbìmọ̀ náà tó ńbọ̀ láti sọ ni fínífíní bí àwọn ènìyàn se dá owó ọ̀ún.

Oluwayẹmisi Dada  

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *