Yoruba

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin n’ípinlẹ̀ ọ̀yọ́ tẹpẹlẹ mọ́ mímú ìgbàdẹrùn si fáràlú

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti sèlérí láti tẹ̀tíwájú nínu sísa ipá rẹ̀ lórí dídábòbò ètò àwọn ọmọbíbí ìpínlẹ̀ yí nípasẹ̀ gbígbé òfin tí yo mú kígbàdẹrùn fáràlú kalẹ.

Alága ìgbìmọ̀ tón rírí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè nílé asòfin, ọ̀gbẹ́ni Seyi Adisa ló sèlérí yi lásìkò tón kópa lórí ètò ilésẹ́ Premier FM tí wọ́n pè lédè gẹ́ẹ̀si.

Ọgbẹni Adisa ẹni tón sojú ẹkùn Afijio, nílé asòfin kẹsan nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ sọ pé ìpínlẹ̀ yí, kò ní fọwọ́ kékeré mú isẹ́ tó wà n’íwájú rẹ̀, láti ri dájú pé àwọn èyàn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ padà àwọn tó wà lókà òkun, ni wọn kòní fàyè gba kí wọ́n fi ìyà àitọ́ jẹ wọ́n.

Lásìkò tón gbóríyìn fún ikọ̀ àwọn asájú nílé asòfin, ọ̀gbẹ́ni Adisa sọ pé ilé asòfin yo pèsè àyíká tó rọrùn fún àjọsepọ̀ múná dóko lárin àwọn asòfin.

Ọlọlade Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *