Ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntí tí wọ́n ńlò ìlànà owó ìfẹ̀yìntì oní dídá, CPUN, ti fi àidùnú wọn hàn lórí ìpinu ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ láti yá nínú àwọn owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n ńdá jọ.

Gẹ́gẹ́bí àtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ alága àjọ tó wà fún owó ìfẹ̀yìntì, Ọ̀gbẹ́ni Samuẹl Kojusọla se sọ, ìgbésẹ̀ yi yio nípa lórí àwọn ètò ìfẹ̀yìntì wọn.

Ẹgbẹ́ náà wá késí àjọ tón rísí ọ̀rọ̀ owó ìfẹ̀yìntì, PENCOM, láti tètè bẹ̀rẹ̀ sísan ìdá mẹ́ẹ̀dógún àti ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àfikún owó ìfẹ̀yìntì láti ọdún 2007 àti tọdún 2010 t’íjọba àpapọ̀ fọwọ́sí.

Wọ́n wá rọ ìjọba ni gbogbo ẹ̀ka láti mú ìgbáyégbádùn àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì lọ́kunkúndùn.

Taiwo Akinọla/Yẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *