Igbákejì alága àjọ tón rísétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nílẹ̀ yíì, NCC, ọ̀jọ̀gbọ́n Umar Danbatta ti mú dáwọn ọmọ orílẹ̀èdè yíì lójú pé, àbò tó péye wà lórí àtọ̀nà ojú òpó tíwọ́n pè ní 5G network, èyí tíwọ́n ló yára ju 4G lọ.

Ó fọwọ́n ìdánilógú yíì sọ̀yà lákokò tó farahàn níwájú àgbáríjọpọ̀ ìgbìmọ̀ tẹkótó ilé asòfin àpapọ̀ tón rí sétò ibaraẹnisọrọ, láti kín àbá ètò ìsúná àjọ NCC, oní billiọnu ẹgbẹ̀ta ó lé diẹ lẹ́yìn tó wáyé nílu Abuja.

Ìgbésẹ̀ yíì lónise pẹ̀lú ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà kan, lórí atọ́na ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun ọ̀hún.

Ọjọgbọn Danbatta tẹnumọ pé, 5G network tawiyii dara púpọ̀ fétò ọ̀rọ̀ ajé àtàmúgbóòrò ilẹ̀ Nàijírìa.

Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *