Yoruba

Bí igba ọdún dìẹ làwọn akẹ́kọ́ọ̀ ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ tó jóko sèdáwò àyẹ̀wò bákẹ̀kọ́ kan se gbéwọ̀n sí láti wọ ile ẹ̀kọ́ girama nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Alákoso fétò ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ̀nsì àti tìmọ̀ ẹ̀rọ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Rahman Abdul-Raheem ló kéde bẹ́ẹ̀ nílu Ìbàdàn, bẹ́ẹ̀ lósì fi ìdùnú rẹ̀ hàn lórí, bẹ́tò ìdánwò náà fún tọdún 2022 yíì se lọ yíká àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó ńbẹ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ lórúkọ, alákoso náà, akọ̀wé àgbà fún ilé isẹ́ ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ yíì, arábìnrin Christianah Abioye sàpèjúwe bí ìdánwò náà se lọ ní ìrọ́wọ́ rẹsẹ̀, tí kò sì sí ìwà màgògágó kankan nínú ètò ìdánwò àsewọlé ilé lkọ́ girama náà.

Ó wá mú dáwọn òbí àtàwọn èèyàn àwùjọ lójú pé, ìjọba tó wà lóde báyíì setán láti dágbogbo àwọn ọmọ tíkò simile we padpa sébẹ̀ lábẹ́ ìlànà ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́

PR/Banjo/Wojuade

Yoruba

Olúbàdàn tilẹ̀ ìbàdàn ọba Lekan Balogun ti sìkìlọ̀ fáwọn atọ́kùn ègùngùn, àtàwọn tó fẹ́ báwọn kọwọ ọdún pé kí wọ́n yàgò fún jàgídíjàgan lásìkò ayẹyẹ ọdún ilẹ̀ ìbàdàn tí yóò bẹ̀rẹ̀ lósù tó n bọ̀.

Ọba Balogun sàlàyé ọ̀rọ̀ yí lásìkò àbẹ̀wò alágbáà tíì se olórí àwọn egùngùn nílé olúbàdàn tó wà ní alárere.

Ọba alayé náà rọ alágbáà pé kí wọ́n ríì dájú pé wọ́n se ọdún náà pẹ̀lú ìrọ̀rùn , ó tẹnumọ́ pé áàfin olúbàdàn kò ní fáàyè gba ẹnikẹ́ni láti tàpá sí òfin nípa síse ọdún egúngún.

Olúbàdàn sèlérí pé, gbogbo àtìlẹ́yìn tó yẹ ni wọ́n yóò ri gbà láti áàfin fún àseyọrí ọdún náà.

Asáàjú àwọn ikọ̀ náà, ẹni tíì tún se alágbáà ti agúgù, ọ̀gbẹ́ni Ọjẹbiyi Adepọju sàlàyé wípé wọ́n se àbẹ̀wò sí áàfin olúbàdàn láti fi tó kábìyèsí láti wípé ìgbáradì fún ọdún egúngún tí yóò wáyé lọdún yí.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Iyawo Gomina Ipinle Oyo, Arabinrin Tamunominimi Makinde ti kesi awon omo ile Nigeria pe ki won dide atileyin fawon obinrin to lugbadi ijamba lasiko abe dida fomobirin.

Arabinrin Makinde soro imoran yi lasiko eto ayajo fifopin si abe dida fomobinrin fun todun yi.

Iyawo Gomina, eni ti alakoso akanse ise nipinle Oyo, Arabinrin Fausat Sanni soju fun tenumo pe ti atileyin ba n wa fun awon obinrin to ba lugbadi isoro lasiko abe dida, eyi yoo tun maa je ona itura fun ru awon ibisi ati onka omoniyan, Dokita Oladosu Ojengbede salaye wipe ipinle Oyo lo wa ni ipo keta awon ipinle to ni akosile isoro abe dida fun omobinrin o salaye wi pe, ipolongo atigbadegba to n lo lee mu adinku ba asa naa.

Alamojuto eto abe dida fomobinrin nipinle Oyo, Arabinrin Balqis Olawonyin naa salaye wipe awon Oloola to n dabe lona ibile lo ti n se ise papo pelu won lati fopin si asa naa.

Baba isale egbe awon oloola nile yi, Oloye Abiola Ogundokun naa salaye wi pe abe dida fomobinrin lewu ju anfani lo, o wa ro won pe ki won jawon ninu asa naa.

Awon to kopa nibi eto naa lo korajo latinu egbe bi PFN, FOMWAN, NASFAT, ati egbe awon agbebi ibile.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Ijoba ipinle Oyo ati ile ise to nrisi pinpin ina oba nilu Ibadan IBEDC, ti yanju awoo to mu ki won ti lara ile ise ton npin na.

Leyin ipade to waye laarin ijoba ati IBEDC  ni ile ise ijoba ipinle Oyo to wa l’Agodi nilu Ibadan,ni  , ni awon mejeeji  so pe won  setan lati sise  papo yanju gbogbo oro to faa ti ijoba ipinle oyo fi gbe awon ofisi IBEDC ti pa.

Ninu atejade ti alakoso fun agbara ati oun alumooni nipinle Oyo, ogbeni Temilolu Ashamu ati oga agba nilese IBEDC, ogbeni John Ayodele fowo si, tokasi pe, igbin mejeji ti jeje lati tesiwaju ninu sise ise papo, fun anfaani awon olugbe  ipinle Oyo.

Won fowo idaniloju soya fun  awon eyan awujo pe, ina oba yo pada bo  sipo laipe laijina .

Bakana ni igbin mejeeji so asoyan oro pe, won yo tesiwaju lati ma sise papo fi je ki ero to n ka  iye  ina oba teyan ba lo, wa larowoto awon olugbe ipinle Oyo.

https://ssl.gstatic.com/ui/v1/icons/mail/no_photo.png
Yoruba

Igbimo Olubadan to fenuko lati maa jee Oloye agba dipo Oba Alayeluwa.

Nigba to n baa won akoroyin soro leyin ipade to waye ni afin Ojaba ti Olubadan ile, Ibadan, Oloye Tajudeen Ajibola so pea won gba igbese gomina lori ipinu re lati da awon pada sori jije Oloye agba.

Lori oro to si w anile ejo Olooye Ajibola, to kosai pe koni nkankan se pelu, ona ti won n gba de ori ite gegebi Olubadan.

O tenumo pe oro to w anile ejo lo ni nkan se pelu tite eto eni loju mole.

Ipade ohun ni awon omo egbe mefa ninu igbimo Olubadanwa nibe latiri Balogun ile ‘Badan, Oloye Agba Owolabi Olakulehin, Otun Balogun Oloye Agba Tajudeen Ajibola, Osi Balogun Oloye Agba Lateef Adebimpe, Asipa Balogun Oloye Agba Kola Adegbola, to fimo Ashipa Olubadan Oloye Agba Eddy Oyewole ati Ekarun Olubadan, Oloye Agba Hamidu Ajibade, Bakana lawon ori ade orun ileke, okere tan Ogun wa nibe to fimo Mogaji meedogun.

Ololade Afonja

Yoruba

Gomina ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti salaye igbiyanju eto isakoso ijoba re lori ati koju ipenija eto aabo nipinle naa.

Gomina Makinde se adayanri oro yi lasiko to n gbalejo asoju awon logaloga ileese olodun to lo fun eto idanileko eleekerinlelogoji ile eko oloogun to wa ni Jaji labe akoso asaaju iko naa, eni tii se ogagun ofurufun Air Vice Marshal Ebenezer Alade.

Nigba to n soro lori akori idanileko won naa ti se mimu idagbasoke ba eto aabo nipase igbiyanju nidi eto amulundun ati oro aje, Gomina Makinde salaye wi pe ijoba re ti ro awon odo lagbara, pelu kikowon kuro loju popo leyi to ti mu ki iwa odaran dinku nipinle Oyo, bee lo tun soo di mimo pe ijoba re, ti pese ina sawon oju popo leyi to mu ki igboro maa wa ni imole lalaale.

Saaju ni oludari iko naa, Air Vice Marshal Ebenezer Alade ti soo di mimo pe won ti yan ipinle Oyo, ninu awon ipinle mejo lorileede yi fun ibi ti abewo lori idanilejo naa yii ti maa waye.

Ayodele Olaopa 

News Yoruba

.

Ewe, Gomina ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde ti sagbekale aba eto isuna odun 2022 niwaju ile igbimo asofin to sipe akori aba eto isuna naa ni aba eto isuna idagbasoke ati anfani.

Nigba to n soro niwaju ile, Gomina lo anfani naa lati jabo iseiriju re gege bo se wa ninu ileri ipolongo ati bi aba eto isuna odun 2021 se se takun-takun.

Akoroyin wa jabo pe Gomina Makinde sagbekale aba eto isuna bilionu odunrun din mefa 294 BN fodun 2022.

Nigba to n soro, adari ileigbimo asofin, Ogbeni Adebo Ogundoyin salaye pe pelu bi aba eto isuna naa se di gbigbe kale lojuojo, yoo fun ile igbimo asofin lanfani ati sagbeyewo re lojuojo.

Kehinde/Olaopa

Yoruba

O se pàtàkì kawon eeyan awujo maa fifehan sawon to ba ti Fara soko logba èwòn rí, lónà àti maa jeki  won tun pass sirufe igbesiaye tiwon n gbe tele, eyi to sokunfa biwon se dogba èwòn.

 Èyí lafenuko àwon olukopa lori ètò olosoose Ile ise wa kan lédè gèésì tapeni focal point.

 Agbenuso ibudo atunse Nile yìí, eka tipinle Oyo, Ògbéni Olanrewaju Anjorin tokasi pe, òpò àwon eléwòn náà layipada òtun ti de ba aye won, tiwon siti gba idanilekoo to yanranti làkókò to won fi wa logba èwòn, Àmó, igbese ideyesi lawujo lo tun maa n dawon pada sese àárò won.

Bakanna , nínú òrò tosise kan, lajo Hope for second chance, Arabinrin Docas Babatunde menuba onirunru ipenija to n koju awon tèwòndé bíi airilegbe , airise se Tofino ideyesi lawujo.

  Folakemi Wojuade

Yoruba

Oludari tuntun fun Ajo Olutaniji Araalu Sojuse Nipinle Oyo (NOA) Arabinrin Folake Ayoola n fe kawon olugbe ipinle yi o wa nigbaradi fun igbokegbodo eto idibo ijoba ibile ti yoo waye losu to n bo.

Arabinring Ayoola pipe ye lasiko to n ba akoroyin Radio Nigeria soro gege bi ara igbiyanju eto ilaniloye oludibo.

Oludari Ajo (NOA) tun ro awon oludibo pe ki won rii daju pe oludije to pegede ni won dibo fun, ti yio le la ipa rere lese kuku.

Arabinrin Ayoola seleri igbaradi ajo wa nidi ipolongo atigba degba fawon odo pe ki won yago fun mongomongo ori ero ayelujara atawon iwa odaran min.

Arabinrin Ayoola wa gba awon araalu niyanju pe ki won maa sora se, ki won si ri daju pe won yago fun irin ale.

Salaudeen

Yoruba

Awon eeyan ipinle Oyo toleni egberun  lona  igba lo je anfani eto ilera ofe eyiti ilese eto ilera ipinle oyo ati ajosepo eto ilera ofe  omititun sagbekale re.

 Eto ohun eyi to bere ni ijoba ibile ila –oorun ibarapa nipinle oyo, lawon eeyan jnafani itoju ofe lori okojokan aisan bi, iba, eje riru, ipenija eyin aisan ayokele foju, ati bebelo.

 Nibi asekagba eto olojo letaelogun ohun, aya gomina ipinle Oyo, Arabinrin Tamunominnini Makinde ro awon eeyan lati mu eto ilera won lokunkundun.

 Arabirin Makinde sope eto ilera ofe ohun, fojusun mimu – agbega ba igbe aye Alafia ati eto oro –aye.

 Alakoso feto ilera nipinle Oyo, Dokita Basher Bello sodi mimo pe eto ohun , totide opo ijoba ibile ipinle Oyo yoo maa waye losu meta – meta.

 Meji ninu awon to je anfani eto naa, ogbeni asimiyu adekunle ati arabinrin toyin babalola gboriyin fun awon to se agbateru eto naa.

Idogbe

Yoruba

Ajo eleto idibo ipinle Oyo, OYSIEC ti sun eto idibo ijoba ibile si ojo kejilelogun soun karun odun yi.

Alaga ajo OYSIEC, Oloye Isiaka Olagunju lo fi ikede naa sita lasiko abewo to se si ajo to n ti si idagbasoke awon agbe, OYSADEP, eyi to wa ni Moore Plantation, Apata, Ibadan.

Oloye Olagunju tenumo pe, o pondadan lati sun ojo idibo naa siwaju lati maa dun awon Musulumi to fe rinrin ajo lasiko odun itunu aawe ni eto won.

Alaga ajo OYSIEC tun toka sip e awon agbe se Pataki fun eto ipolongo ajo naa leyi to se okunfa abewo sodo won kadinku o lee ba akude to le fe way lasiko eto idibo ijoba ibile to n so.

O salaye wi pe won yio gbe ise oruko oludibo jade laipe, o wa ro awon ti kaadi idibo alalope won ba ti baje pe ki won toju iwe idanimo ile yi, tabi iwe ase iwako lati le fun won lanfaani ati kopa nibi idibo naa.

Ninu oro re, Alaga Ajo OYSADEP, Alhaji Salihu Imam gba awon araalu nimoran pe ki won tu yaapaa jade fun eto idibo to n bo naa lati yan eni to wuwon si joba ibile.

Salaudeen

News Yoruba

 Ijoba ipinle oyo ti fowosi ipese akanse iwe idibo gege bi ohun elo Pataki feto idibo ijoba ibile ti yoo waye nipinle oyo laipe pelu owo to to igba ati mokandinlegorin naira.

Alakoso eto iroyin ohun oro asa nipinle oyo, omowe wasiu oaltunbosun lo foju oro yi lele pelu alaye wi pe owo to to igba ati ogota million naira ni won ti fowosi  fun ipese akanse iwe idibo to to million meji ati egbeta naira leyi to tumo sip e won too pese iwe idibo kan pelu ogorun kan naira, to million mokandinlogun ataabo naira yoo si wa gege bi afikun.

Omowe  olatunbosun tun soo di mimo pe ijoba ti gbe ise agbase iwe idibo tite was fun ileese to n te nnkan bonkele lorileede yi to was nilu eko.

Ewe , alakoso ise ode ati eto irinna nipinle oyo, ojogbon david sangodoyin soo di mimo pe won ti fowosi ise akanse ilegbe ti yoo je tijoba ipinle oyo to je tigbalode silu Abuja pelu owo to to billionu kan ati igba million naira.

Adebisi/Salaudeen

Yoruba

Ijoba Ipinle Oyo ti pese owo iwuri oju ese fawon iko elere idaraya ton soju ipinle Oyo ti won ti gba ami eye nibi idije ere idaraya ile yi ton lo lowo nipinle edo.

Nigba ton fun won ni owo naa nibudo ti won pago si nile eko giga Fasiti Benin Alaga Ajo Elere Idaraya Ipinle Oyo, Oloye  Gbenga Adewusi salye wi pe igbese yi lo le je koriya fawon elere idaraya akegbe won ti won jo n soju Ipinle  Oyo  lati ri daju pea won wa gba ami eye.

 Oloye adewusi salaye wi pe igbese ebun owo fawon elere idaraya yi lo je Igbiyanju Gomina Seyi Makinde lati fi gbe won laruge

Oloye Adewusi soo do mimo pe ileese oun lo fun won ni egberun marun, nigba to oga agba ajo elere idaraya Ipinle Oyo Ogbeni Gbenga Makinde naa fi egberun marun kun ogun egberun naira tijoba Ipinle Oyo so pe ki won maa fun elere idaraya to ba gba ami goolu.

 Awon elere idaraya meji to ti gba ami goolu lo tewo gba egberun lona ogbon enikookan, nigba tawon merin to gba ami wura gba egberun mewa naira enikookan, ti awon mejidinlogun to gba ami fadaka si gba egberun marun naira  enikookan .

Salaudeen

News Yoruba

Gomina ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde ti so pe isejoba re, yo satunse lori opopona to je ti igberiko ti ko ni din ni ibuso igba niye niipase ise akanse to wa fun ese kuku ati tita-rira nkan eka ogbin ramp fun todun 2021.

O soro yi, lasiko ti on ngba asoju Bank idagbasoke ile adulawo ati ajo eleto isuna agbaye fun idagbasoke ise agbe IFAD, llalejo loofisi re.

Gomina ni isejoba re, ni on sise lati ri daju pe agbega deba eka ohun ogbin nipinle yi ti yio si mu goke agba debi ipo amuye, ti yo si fun pese ise fun opo odo ti moni ise lowo.

Gomina Makinde tun gboriyin fun ise akanse RAAMP, lori akitiyan lati tun opopona to wa nigberiko to wo ibuso igba niye se.

Saaju, eni to lewaju iko Banki idagbasoke ile adulawo, Omowe Chucks Ezedinma sope ile ifowopamo naa lo n sise lowo lati sise Pataki lori siso nkan oko di nkan mira, wro yi ni won yo si se agbekale re si ipinle mefa tipinle Oyo si je okan.

Adebisi/Afonja

Yoruba

Bí àgbáyé se ń sàmíì àyájọ́ ọjọ́ àwọn olùkọ́ adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ti sàpèjúwe àwọn olùkọ́ gẹ́gẹ́ bí igilẹ́yìn ọgbà ìdàgbàsókè àwùjọ tí ó sepàtàkì láti máà mọrírì nígbàgbogbo.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkínni rẹ̀ fún àyájọ́ àwọn olùkọ́ fún tọdún yíì, ọ̀gbẹ́ni Ogundoyin kí àwọn olùkọ́ nílẹ̀ Nàijírìa àti ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kú oríre, ayẹyẹ ohun èyítí àjọ UNESCO sèdásílẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 1994.

Adarí ilé sọpé kòsí ẹni yóòwu tó se àseyọ́rí tí kóò gba iwájú olùkọ́ kọ́ọ̀já, pẹ̀lú àlàyé pé, fífi ọjọ́ kan mọ́ọ̀ rírì wọn sepàtàkì.

kehinde/idogbe

Yoruba

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti sèlérí láti tẹ̀tíwájú nínu sísa ipá rẹ̀ lórí dídábòbò ètò àwọn ọmọbíbí ìpínlẹ̀ yí nípasẹ̀ gbígbé òfin tí yo mú kígbàdẹrùn fáràlú kalẹ.

Alága ìgbìmọ̀ tón rírí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè nílé asòfin, ọ̀gbẹ́ni Seyi Adisa ló sèlérí yi lásìkò tón kópa lórí ètò ilésẹ́ Premier FM tí wọ́n pè lédè gẹ́ẹ̀si.

Ọgbẹni Adisa ẹni tón sojú ẹkùn Afijio, nílé asòfin kẹsan nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ sọ pé ìpínlẹ̀ yí, kò ní fọwọ́ kékeré mú isẹ́ tó wà n’íwájú rẹ̀, láti ri dájú pé àwọn èyàn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ padà àwọn tó wà lókà òkun, ni wọn kòní fàyè gba kí wọ́n fi ìyà àitọ́ jẹ wọ́n.

Lásìkò tón gbóríyìn fún ikọ̀ àwọn asájú nílé asòfin, ọ̀gbẹ́ni Adisa sọ pé ilé asòfin yo pèsè àyíká tó rọrùn fún àjọsepọ̀ múná dóko lárin àwọn asòfin.

Ọlọlade Afọnja

Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde sọpé ètò ìsèjọba tóun ńléwájú rẹ̀ kóní tẹ̀tì láti gùnlé àwọn ìpinnu èyí tí yóò fẹsẹ̀ ìdàgbàsókè tóò lórin múlẹ̀ nípinlẹ̀ Ọyọ.

Ó sọ èyí nígbà tó ńgba àbọ̀ ìwádi ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje, èyítí ìsèjọba rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti wòye sí oníruru ìpèníjà tó ńkojú ìpínlẹ̀ yíì, lọ́fìsì rẹ̀ nílu ìbàdàn.

Gómìnà Makinde wá bèrè fún àbá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àwùjọ láti mú ìpínlẹ̀ Ọyọ gòkè àgbà pẹ̀lú àlàyé pé irúfẹ́ àbá bẹ yóò sisẹ́ lọ́pọ̀ fágbege ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Bákanà ni Gómìnà fidá àwọn èèyàn lójú pé, àbọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ náà yóò jẹ́ sísàmúlò lárin ọ̀sẹ̀ mẹ́rin.

Gómìnà tọ́kasi pé àbọ̀ ìwádi ìgbìmọ̀ náà tọ́kasi dídá àwọn òsìsẹ́ kan dúró lọ́nà àitọ́, tó sì sàlàyé pé ìjọba yóò ságbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ náà tí yóò sì dá àwọn tóbáyẹ padà sísẹ́ lẹ́yẹ òsokà.

Kẹmi Ogunkọla/Dada Oluwayẹmisi