Yoruba

Olúbàdàn t’ilẹ̀ ‘bàdàn sèkìlọ̀ fáwọn égúngún láti yàgò fún ìwà jàgídíjàgan lákokò ọdún wọn.

Olúbàdàn tilẹ̀ ìbàdàn ọba Lekan Balogun ti sìkìlọ̀ fáwọn atọ́kùn ègùngùn, àtàwọn tó fẹ́ báwọn kọwọ ọdún pé kí wọ́n yàgò fún jàgídíjàgan lásìkò ayẹyẹ ọdún ilẹ̀ ìbàdàn tí yóò bẹ̀rẹ̀ lósù tó n bọ̀.

Ọba Balogun sàlàyé ọ̀rọ̀ yí lásìkò àbẹ̀wò alágbáà tíì se olórí àwọn egùngùn nílé olúbàdàn tó wà ní alárere.

Ọba alayé náà rọ alágbáà pé kí wọ́n ríì dájú pé wọ́n se ọdún náà pẹ̀lú ìrọ̀rùn , ó tẹnumọ́ pé áàfin olúbàdàn kò ní fáàyè gba ẹnikẹ́ni láti tàpá sí òfin nípa síse ọdún egúngún.

Olúbàdàn sèlérí pé, gbogbo àtìlẹ́yìn tó yẹ ni wọ́n yóò ri gbà láti áàfin fún àseyọrí ọdún náà.

Asáàjú àwọn ikọ̀ náà, ẹni tíì tún se alágbáà ti agúgù, ọ̀gbẹ́ni Ọjẹbiyi Adepọju sàlàyé wípé wọ́n se àbẹ̀wò sí áàfin olúbàdàn láti fi tó kábìyèsí láti wípé ìgbáradì fún ọdún egúngún tí yóò wáyé lọdún yí.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published.