News Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé ìjọba rẹ̀ fún ọdún méjì àkọ́kọ́ ti mú àlékún bá owó tí wọ́n ń pa wọlé lábẹ́nú pẹ̀lú owó tótó billionu mẹ́ẹ̀dogun naira lái se àlékún owó orí.

Gómìnà sàlàyé ọ̀rọ̀ yí níbi ètò kan tó wáyé nílu ìbàdàn lásìkò tón fèsì sí àwọn àhesọ kan nípa ìlànà ìkówójọ fún isẹ́ ìdàgbàsókè tíjọba rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti fi di àlafo ìpèsè ùnkan amáyédẹrùn àti láti se àmúgbòrò ètò ọ̀rọ̀ ajé léyi ti yóò tún lé mu kí àgbéga bá ìlànà ìpawówọlé lábẹ́nú.

Gómìnà Makinde sàlàyé wípé àkọsílẹ̀ àjọ tó ń sètò ìsirò nílẹ̀ yí se àfihàn rẹ̀ pé àlẹ́kún ìdá méjìlélógójì ló ti bá ọ̀nà ìpawówọlé lábẹ́nú nípa bí àwọn tón san owó orí se pọ síì lái se àlékún owó orí.

Gómìnà tún sèkìlọ̀ lórí titi owó òsèlú bọ́ ìpèníjà tó ń kojú ètò áàbò nípinlẹ̀ ọ́yọ̀ pẹ̀lú àlàyé wípé léyi tí wọ́n yóò fi máà se alátakò láì la ọ̀nà àbáyọ, ó yẹ kí koriwa ó kópa nínú ìgbésẹ̀ àti jẹ́ kí ètò áàbò tó péye ó wá ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Adebisi /Salaudeen

Yoruba

Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti kan sárá síjọba lórí àsẹ tuntun nípa sísọ ètò kólẹ̀kódọ̀tí olósosù di ọlọ́sẹ̀sẹ̀.

Wọ́n gbósùbà yi lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn Radio Nigeria tó tọpinpin báwọn èèyàn se tẹ̀lé àsẹ náà si.

Wọ́n tún rọ àwọn rọ àwọn aráalu pé kí wọ́n mú ìmọ́tótó àyíká wọn lọ́kunkúdùn láti fi le ja àjàbọ́ lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn.

Ọkan lára àwọn èèyàn náà, arábìnrin Bọlanla Taiwo sàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀ wí pé ìdọ̀tí ọ̀hún ẹ̀gbin àyíká ló léè sokùnfà àjàkálẹ̀ àrùn láwùjọ.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ náà, onísòwò kan, ọ̀gbẹ́ni Samuel Ọlanrewaju pàrọwà síjọba pé kí wọ́n pèsè goro ìdalẹ̀sí sáàrin ìlú láti dènà dídalẹ̀ sójú àgbàrá.

Ọgbẹni Ọlarenwaju tún késí àwọn òsìsẹ́ woléwolé pé kí wọ́n máà tọpinpin ètò kólẹ̀kódọ̀tí náà láti fi ríì dájú pé àwọn èèyàn kópa tó yẹ.

Akọ́ròyìn Radio Nigeria sàkíyèsi pé àwọn òutàgà lárin ọjà ńlá bíì Mọniya, Ọjọọ, U.I, Sango, Mọkọla, Dugbẹ àtàwọn ọjà min tilẹ̀kùn isẹ́ wọn láti fi bétò ìmọ́tótó àyíká wọn.

Ọlayiwọla/Salaudeen

News Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ti pinnu lórí àfojúsùn rẹ̀ láti mágbega báwọn ohun amáyédẹrùn yíká àwọn iléwe gbogbo tónbẹ nípinlẹ̀ yíì àti se àkànse kíkọ́ àwọn ilé-ìwé tó ti dẹnukọlẹ̀.

Gómìnà Seyi Makinde ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì, lákokò tó ń pín ìwé ìkọ́sẹ́ lọ́fẹ fáwọn akẹ́kọ ilé-ìwé girama tọ́rọkàn nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Kò sài rọ àwọn tọ́rọ kàn, láti yàgò fósèlú síse, kíwọ́n máà kín akitiyan ìjọba lẹ́yìn, lọ́nà àti fìrètí ọjọ́ ọ̀la tó dájú àwọn akẹ́kọ́ọ̀ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ múlẹ̀ daindain.

Gómìnà kò sài tún tọ́kasi pé, wọ́n ti fọwọsí owo tíwọ́n fẹ́ lò fátunse àwọn ilé-ìwé tó jẹ́ tìjọba nípinlẹ̀ yíì, pẹ̀lú ìlérí pé ìjọba kòní káàrẹ láti pèsè àwọn owóna tóyẹ sẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Sáajú lálákoso fétò ẹ̀kọ́imosayẹbi àtimọ̀ ẹ̀rọ nípinlẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Ọlasunkanmi Ọlalẹyẹ sàlàyé pé, ìgbésẹ̀ ìwé pínpín náà, ló wà níbamu pẹ̀lú ìlànà ìjọba láti pèsè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, pẹ̀lú àtọ́kasí bí milliọnu méjì àtáàbò niwọ́n yóò pin fáwọn akẹ́kọ tónbẹ yíká àwọn ilé-ìwé ìjọba nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Adebisi/Wojuade

Yoruba

Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ni yio gbàlejò ìdíje ẹ̀sẹ́ kínkàn àgbáyé ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n osù yí.

Alága ìgbìmọ̀ tó ńse kòkárí ìdíje náà Ọlawale Okuniyi ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yí lásìkò tó kó ikọ̀ ìgbìmọ̀ rẹ̀ sòdí wá gbé bẹ́lìtì ìdíje náà wá han Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde lọ́fìsì rẹ̀ tó wà l’Ajodi nílu ìbàdàn.

Nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ lórí ìdíje náà, ọ̀gbẹ́ni Okuniyi ní ọdún 1963 ni ìlú ìbàdàn ti gbàlejò irú ìdíje yi gbẹ̀yìn ní pápá ìseré Liberty tíì se ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta sẹ́yìn.

Ó ní àkànse ọmọ ilẹ̀ yí Rilwan Adekọla tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Scopion tíì se ọmọbíbí ìlú ìbàdàn ni yio máà wáàko pẹ̀lú Lucas Matia Montesino ọmọ ilẹ̀ Argentina.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Gómìnà Makinde ẹnití akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Olubanwo Adeosun gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ni ìdàgbàsókè eré ìdárayá jẹ ìjọba lógún, ó wá jẹ́jẹ pé ìjọba tó wà lóde báyi yio sàtìlẹ́yìn tótọ́ fún ìdíje náà.

Gómìnà Makinde wá rọ abẹ̀sẹ́kùbí òjò náà láti jà fitafita láti léè gbé orúkọ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ àti ilẹ̀ Nàijírìa lékè nínú ìdíje tó ńbọ̀ lọ́nà náà.

Adebisi/Dada Yẹmisi

Yoruba

Lóòrọ̀ òní, àwọn òsìsẹ́ ọba ni kò rọrùn fún láti wọ ilésẹ́ ìjọba ní Secretariat, Agodi ìbàdàn, lẹ́yìn tí àwọn tó ní ìpèníjà ara ńfẹ̀húnúhàn lórí ẹ̀sùn pé ìjọba dẹ́yẹ sí wọn.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria jábọ̀ pé àwọn àkàndá ẹ̀dá yi ni wọ́n ńgbé oníruru àkọlé lọ́wọ́ láti fi ẹ̀húnúhàn wọn hàn.

Àwọn tón fẹ̀húnúhàn yi, fẹ̀sùn kan ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ pé, wọ́n kò fi àwọn sínú àwọn tí wọ́n gbà sísẹ́ láipẹ yi, tí àjọ tón mójútó ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ se agbátẹrù.

Akọ̀ròyìn jábọ̀ pé àwọn ẹ̀sọ́ alábo wànkẹlẹ láti fẹsẹ̀ òfin múlẹ̀.

Ayọade/Afonja

Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde ti sèlérí pé òun yóò ridájú pé òun dun ẹbí àwọn ọlọ́pa tíwọ́n sekúpa lákokò ìfẹ̀húnúhàn fífòpinsí ikọ̀ SARS, nínú tóun yóò sì sàtúnse sáwọn ilé-isẹ́ ọlọ́pa tíwọ́n bà jẹ́.

Níbi ìpàdé àláfìa kan tí Gómìnà se pẹ̀láwọn ọ̀gá àgbà ilé-isẹ́ ọlọ́pa ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tó wáyé lólúlesẹ́ náà, ládugbò Ẹlẹ́yẹlé nílu ìbàdàn, ló ti fọwọ́ ìdánilójú náà sọ̀yà.

Nígbà tón se ìbánikẹ́dùn pẹ̀láwọn ọ̀gá ọlọ́pa náà lórí ikú àwọn òsìsẹ́ wọn tólọ, Gómìnà Makinde wá rọ̀wọ́n láti gbàgbé gbogbo àwọn ǹkan tóti sẹlẹ̀ ní ǹkanbi ọ̀sẹ̀ diẹ sẹ́yìn.

Kò sài tún bèèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọlọ́pa ọ̀hún pẹ̀lú ètò ìsèjọba rẹ̀, tófimọ́ wọn èèyàn min tọ́rọ̀kan lọ́nà àti jẹ́ káwọn èèyàn máà ní nígbàgbọ́ nínú wọn lákokò tíwà bá ń fẹsẹ òfin àti ìlànà múlẹ̀ láwùjọ.

Sáájú nínú ọ̀rọ̀ t’ígbákejì ọ̀gá àgbà pátápátá fọ́rọ̀ ọlọ́pa, tó wà fẹ́kùn ìwọ̀óòrùn gúsù, Ọ̀gbẹ́ni Lẹyẹ Oyebade, késáwọn òsìsẹ́ abẹ́ rẹ̀ nípinlẹ̀ yíì láti sisẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tí Gómìnà sọ, kíwọ́n sì ridájú pé àláfìa jọba yíká.

Nínú ọ̀rọ̀ tiwọn náà, alákoko fọ́rọ̀ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Joe Enwonwu àtọ̀gágun àgbà Adesọji ọ̀wọ́ kejì dìjọ rọ àwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa láti máà sisẹ́ wọn níbamu pẹ̀lú àsẹ ọ̀gá àgbà pátápátá fọ́rọ̀ ọlọ́pa nílẹ̀ yíì, Ọ̀gbẹ́ni Muhammed Adamu.

Iyabo Adebisi/Folakemi Wojuade