Didokowo sórí ọmọbìnrin nípa ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ tó yé kooro yóò ṣe atileyin tí kò kéré fún wọn nínú gbogbo ìdáwọ́lé wọn nígbà tó bá yẹ kí wọ́n wúlò. 

 Ìyàwó Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, arábìnrin Tamunominini Makinde ló sọ̀rọ̀ ìyànjú yi fún isami ayajo àwọn ọmọbìnrin lagbaye. 

Arábìnrin Makinde ẹni tó ṣàpèjúwe ìwà aimmooko mooka gẹ́gẹ́ bí ìṣòro tó leè kojú èèyàn láti má ní ìgbọ́kànlé nínú ara ẹni ṣàlàyé wípé kí obìnrin náà leè lẹ́nu ọ̀rọ̀, ètò ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì fún wọn. Arábìnrin Makinde wá ṣekíló fáwọn ọmọbìnrin pé kí wọ́n yàgò fún ìwà yòówù tó bá lee pagidina ọjọ́ ọ̀la rere fún ùn.

Alakoso ètò ẹ̀kọ́ nipinle Ọ̀yọ́, Ogbeni Olasunkanmi Olaleye náà ṣàpèjúwe yíya obìnrin nípòsìn gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò bójúmú, ó tẹnumo pé ìgbése tó yẹ gbọdọ máà jẹ́ gbígbé lórí ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọbìnrin òpò àwọn akeko tó lé ní ẹgbẹ̀rin tí wọ́n kọ jọ láti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ káàkiri Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé kí wọ́n mú ìtọ́jú àwọn ọmọbìnrin lókun kúndùn, kí wọ́n sì faaye dogbandogba sílè fáwọn obìnrin.

Lára ohun tó wáyé níbi ètò náà ni ìjọba ìbílẹ̀ àti fífún àwọn iléèwé tó kópa níbi ètò náà lẹ́bùn. 

Adebisi/Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *