Tag: Ìjọba àpapọ̀

  • Ìjọba Àpapọ̀ Fèsì Lórí Bílẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì Se Yọ Orúkọ Ilẹ̀ Nàijírìa Kúrò Nínú Orúkọ Àwọn Orílẹ̀èdè Téwu Àjàkálẹ̀ Wà

    Ìjọba Àpapọ̀ Fèsì Lórí Bílẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì Se Yọ Orúkọ Ilẹ̀ Nàijírìa Kúrò Nínú Orúkọ Àwọn Orílẹ̀èdè Téwu Àjàkálẹ̀ Wà

    Ìjọba àpapọ̀ ti fìdùnú rẹ̀ hàn lórí bí ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì se yọ ilẹ̀yí kúrò nínú ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀èdè téwu àjàkálẹ̀ àrùn wà nílẹ̀ àgbáyé pẹ̀lú bí wọ́n se fòpin de balù ilẹ̀yí láti máse wọ ìlú gẹ́ẹ̀si nípasẹ̀ ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn Omicron tẹlẹ. Ọga àgbà ẹ̀ka ìkànsáralu nílé isẹ́ tón rísí ìgbìkègbodò òfurufú, Dókítà…

  • Wọ́n Ti Gba Ìjọba Àpapọ̀ Níyànjú Láti Sàgbékalẹ̀ Òfin Kan Tí Yóò Pa Abẹ́rẹ́ Àjẹsára Gbígbà Ní Dandan Fáwọn Ọmọdé

    Wọ́n ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti sàgbékalẹ̀ àwọn òfin kan tí yóò pa abẹ́rẹ́ àjẹsára ní dandan fáwọn ògo wẹrẹ, lọ́nà àti dábobo wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn àtàisàn lọ́kọ́kan òjọ̀kan. Akọ̀wé àgbà àjọ tón bójútó ètò ìlera alábọ́dé nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ Dókítà Muyideen Ọlatunji ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákokò tónkópa lórí ètò ọlọ́sọ̀ọsẹ̀ ilé-isẹ́…

  • Ìjọba Àpapọ̀ Yóò Kojú Oro Sáwọn Tó Bá Ń Ba Dúkia Ilé Isẹ́ Panápaná Jẹ́

    Alákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla ti sọpé ìjọba àpapọ̀ yóò sisẹ́ lórí àwọn ọ̀daràn tó n sèkọlù sí àwọn òsìsẹ́ panápaná àti àwọn dúkia ilé isẹ́ náà jákèjádò ilẹ̀ Nàijírìa. Ọgbẹni Arẹgbẹsọla yọjú ọ̀rọ̀ náà síta lásìkò tón sísọ lójú ọkọ̀ panápaná olówó iyebíye tuntun tíjọba àpapọ̀ kó lọ sílé isẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Taraba…

  • Ìjọba Àpapọ̀ Dába Àjọsepọ̀ Lárin Àwọn Ilésẹ́ Tón Sisẹ́ Ìwádi Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀

    Ìjọba àpapọ̀ ti fẹ́ sèdásílẹ̀ ibùdó ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ọgbọ́n àtinúdá mẹ́fà sáwọn ẹkùn ibùdó mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà lórílẹ̀ èdèyí. Ìgbésẹ̀ yí jẹ́ láti sàmúlò àwọn àbọ̀ isẹ́ ìwádi láti fi pèsè àwọn ohun èlò tó léè tankàngbọ̀n lágbayé. Alákoso fọ́rọ̀ ìmọ̀ sciensi, ìmọ̀ ẹ̀rọ àri ọgbọ́n àtinúdá, Ogbonnaya Onu, ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò tó…

  • Ijoba Apapo Gbe Igbese Pinpin Owo Lati Madinku Ba Ipa Aarun COVID-19

    Ijoba apapo pelu ajosepo banky agbaye, yoo pin egberindinlaadota million dollar ni ipinle merindinlogoji to w anile yi, lati madinku ba ipa aarun covid-19. Alakoso keji feto isunaa ati aato gbogbo, Ogbeni Clem Agba so eyi nilu Abuja. O salaye pe, ipinle kokan yoo gba ogun million dollar, nigba tii million medoogun dollar yo je…

  • Ìjọba Àpapọ̀ Ti Fi Ikọ̀ Amúsẹ́yá Ránsẹ́ Sí Ìpínlẹ̀ Kano Lórí Àisàn Kan Tó Bẹ́ Sílẹ̀

    Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè yíì ti rán ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá lọ sípinlẹ̀ Kano, láti ló kápá àisàn pàjáwìrì kan tó bẹ́sílẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀hún. Olùdarí àgbà pátápátá fún ibùdó tón rísí ìkápá àrùn lọ́lọ́kanòjọ̀kan nílẹ̀ yíì, NCDC, Dókítà Chikwe Ihekweazu ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì nílu Abuja lákokò ìpàdé alájùmọ̀se kan tígbìmọ̀ amúsẹ́yá tílesẹ́ àrẹ gbékalẹ̀ covid-19. Ó…

  • Ìjọba àpapọ̀ dẹ̀bi ìrìnà lọ́nà tí kò bófinmu ru bétò àbò lẹ́nu ìloro se mẹ́hẹ

    Alákoso fóun abẹ́lé lórílẹ̀dè yíì, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla, sọpé aléèkún tó ńbá àwọn arìn-rìn àjò tí wọ́n sètò ìrìnà lọ́nà àitọ́ níì bétò àbò lẹ́nu ìloro se ti mẹ́hẹ. Alákoso ké gbàjarè yíì, níbi ìpàdé tóse pẹ̀lú àwọn asojú àjọ ìsọ̀kan ilẹ̀ Europe èyítí asójú ilẹ̀ Nàijírìa àti Ecowas, Ketil Karlsen léwájú. Ó sàlàyé pé…

  • Ìjọba Àpapọ̀ Ńgbèrò Láti Gba Àwọn Akẹ́kọ Jáde Nílé Ẹ̀kọ́ Gíga Sẹ́nu Isẹ́ Lẹ́ka Ètò Ọ̀gbìn

    Ìjọba àpapọ̀ ti setán láti gba àwọn akẹ́kọ jáde, ilé ẹ̀kọ́ gíga ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n níye sẹ́nu isẹ́ lẹ́ka ètò ọ̀gbìn láti sàtìlẹyìn fáwọn àgbẹ̀ yíká orílẹ̀ èdè yí. Akọ̀wé àgbà, fún ẹgbẹ́ tón mójútó ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ilẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Paul Ikonne ló sọ̀rọ̀ yí fáwọn akọ̀rìnyìn nílu Abuja pẹ̀lú àlàyé pé àwọn akẹ́kọ…

  • Ìjọba àpapọ̀ ké sáwọn èèyàn láti máà se fi ìbẹ̀rù bojo ra sìmẹ́ntì sọ́wọ́

    Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀dè yíì ti sèkìlọ̀ fáwọn èèyàn àwùjọ láti máà se lọ fi ìbẹ̀rù bojo rọ èrónjà cement sowo, mítorí bówó rẹ̀ seti gbẹ́nusókè láwọn apá ibikan lórílẹ̀dè yíì. Àtẹ̀jáde kan tílesẹ́ olókóòwò, àti ìdásẹ́ ajé sílẹ̀, fisíta sọpé, ilé-isẹ́ náà ń sisẹ́ takuntakun láti lọ́wọ́ àwọn tọ́rọkàn sẹ́ka tón pèsè, èròjà cement láti…

  • Ìjọba àpapọ̀ mú àtúnse bá ètò ilégbe fáwọn èèyàn tí kò rọ́wọ́ họrí

    Ètò àgbékalẹ̀ ilégbe tó jẹ́ ọ̀kan gbogi nídi fífẹsẹ̀ èróngbà ìdúrósinsin ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yíì múlẹ̀, làfojúsùn rẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ ìrọ̀rùn fáwọn èèyàn tówó tó ń wọlé fún wọn, kó tó ùnkan. Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fáarẹ Muhammadu Buhari lórí ọ̀rọ̀ ìgbáyégbádù, arábìnrin Imeh Okoh tó fìdí èyí múlẹ̀ nílu Abuja, sọpé, ètò náà kò wà…

  • Ìjọba àpapọ̀ sèlérí láti mú ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn rúgọ́gọ́ si nípasẹ̀ ìrólágbára.

    Ìsèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari yóò tẹ̀wáwájú ní di mímọ́rọ̀ ìdàgbàsókè ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn lọ́kunkúdùn nípasẹ̀ ètò ìrónilágbára fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin tí yóò se kóríyá fún láti fi yan ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn láàyo. Alága ìgbìmọ̀ níbùdó tón rísísẹ́ ìwádi nípa ọ̀gbìn ewébẹ̀, NIHORT, Ajagun fẹ̀yìntì Garba Muhammed, ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákokò tó ń síde ètò ìdánilẹ́kọ ọlọ́jọ́ kan lórí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin nílu Ìbàdàn.  Ọgagun àgbà Muhammed wá sàpèjúwe ìdánilẹ́kọ fáwọn ọ̀dọ́ tí kò nísẹ́ lọ́wọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí ara àayan ìjọba àpapọ̀ láti mágbende bá ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀dè yíì. Sáàjú nínú ọ̀rọ̀ ọ̀gá àgbà ibùdó NIHORT, nílu Ìbàdàn, ọ̀mọ̀wé Abayọmi Ọlaniyan jẹ́jẹ àtìlẹ́yìn ibùdó náà láti pèsè àwọn onímọ̀ tí yóò sisẹ́ papọ̀ pẹ̀láwọn tó jànfàní ètò ìdánilẹ́kọ ọ̀hún, fimu kí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó tamọ̀sí PineApple rúgọ́gọ́si.  Mẹ́ta lára àwọn tó jànfàní ètò náà, David Forunso, Ọlaitan Ọlalẹyẹ, àti Dorcas Damilọla gbóríyìn fún ìjọba àpapọ̀, tíwọ́n sì sèlérí pé àwọn yóò sàmúlò ìmọ̀ táwọn ríkọ́ níbi ètò náà dada,…

  • ìjọba àpapọ̀ fẹ́ fòpinsí bí ìlésẹ́ apínáká se n bu owó iná fáwọn oníbarà

    Àarẹ orílẹ̀dè yíì, Muhammadu Buhari ti tẹnumọ́ ìpinnu ìjọba tó wà lóde báyíì láti fòpinsí báwọn ilé-isẹ́ apínná ká se máà ńbu owó láibítà fáwọn oníbarà wọn nílẹ̀ Nìajírìa. Àarẹ Buhari tó sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ nílu Abuja, tó sì sàlàyé pé, ìsèjọba òun yóò ridájú pé, iye iná ọba táwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì bá…

  • Ìjọba Àpapọ̀ Fi Ọkàn Àwọn Èyàn Àwùjọ Balẹ̀ Lórí Àbá Òfin Lórí Omi

    Ìjọba àpapọ̀ ti sọ pé kòsí on ìkọ̀kọ̀ kankan lórí àbá òfin lórí omi èyí tí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ńgbé yẹ̀wò lọ́wọ́. Níbi àpérò kan nílu Abuja ni alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn àti àsà, Àlhájì Lai Mohammed àti alákoso fún ọ̀rọ̀ tóníse pẹ̀lú omi, ọ̀gbẹ́ni Suleiman Adamu, sọpé ọ̀pọ̀ àwọn tón kọminú lórí àbá òfin…

  • Ìjọba àpapọ̀ sèlérí fáwọn òntàjà ọmọ ilẹ̀ yíì tówà lórílẹ̀èdè Ghana

    Igbákejì àarẹ orílẹ̀èdè Nàijírìa Yẹmi Ọsinbajo ti fidá àwọn ọmọ ilẹ̀ yíì tó ńtajà lórílẹ̀èdè Ghana lójú wípé ìdájọ́ òdodo yówayé lórí ohun tí wọ́n jìjàdù rẹ̀ pẹ̀lú ìjọba ilẹ̀ Ghana. Ọjọgbọn Ọsinbajo, ẹnitó sèpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn asojú ọmọ ilẹ̀ yíì tíwà ni Accra, Ghana fọwọ́ ìdánilójú ìpinu ìjọba àpapọ̀ sọ̀yà, láti dásí ọ̀rọ̀…

  • Ìjọba àpapọ̀ ti ń gbèrò láti sàtìlẹyìn fún ìlànà sìsanwó àwọn olùkọ́ ilé-ìwé aládani

    Igbákejì àarẹ orílẹ̀dè yíì, ọ̀jọ̀gbọ́ Yẹmi Ọsinbajo sọpé, ìjọba àpapọ̀ ti nì óuń yóò sàtìlẹyìn fún ìlànà sìsanwó osù àwọn olùkọ́ ilé-ìwé aládaní àtàwọn onísẹ́ ọwọ́, láti pinwọ́ ipá tí ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19 timì lórí ètò ọrọ̀ ajé wọn. Níbi ètò àpérò ọlọ́dọọdún tẹ́gbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò tónlọ lọ́wọ́ ọgọ́ta irú ẹ̀, lọ̀jọ̀gbọ́n Ọsinbajo ti sísọ…

  • Ìjọba àpapọ̀ kò fọwọ́sí àfikún iye ọdún tí òsìsẹ́ yólo lẹ́nusẹ́

    Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí, ọ̀mọ̀wé Fọlasade Yẹmi-Esan ti sọ pé ìjọba àpapọ̀ kò fọwọ́sí àfikún iye ọdún tí òsìsẹ́ yo lò lẹ́nusẹ́ ọba. Àtẹ̀jáje èyí tí olùdarí fọ́rọ̀ ìròyìn, arábìnrin Ọlawumi Ogunmosunle fisíta tọ́kasi pé olórí òsìsẹ́ kò fọwọ́ irúfẹ́ ìwé yi lára. Ọmọwe Yẹmi Esan wá rọ àwọn òsìsẹ́ ọba àti àwọn èyàn àwùjọ…