Àwọn ilé epo nílu ìbàdàn ni wọ́n ò tẹ̀lé àsẹ láti mú àdínkù bá owó tí wọ́n ńta jálá bẹntirol sí naira méjìlélọ́gọ́jọ gẹ́gẹ́bí ìjọba àpapọ̀ tise pàsẹ rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá.

Akọ̀ròyìn ilé isẹ́ Radio Nigeria tó sàbẹ̀wò sáwọn ilé epo kan lágbègbè Apẹtẹ, Mọ́kọ́lá, Sángo àti Dùgbẹ̀ sàkíyèsi pé naira méjìdínláadọsan ni wọn sì ńta jálá epo bẹntirol kan.

Ọkan lára àwọn òntàjà epo tí kò fẹ́kí àwọn dárúkọ rẹ̀ ni àwọn ó tíì rí àsẹ gbà látọ̀dọ̀ àjọ tọ́rọkàn láti já owó epo wálẹ̀ pẹ̀lú naira márun.

Ó ní bí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sì níì ta epo lówó tuntun yí àwọn òntàjà epo ni yio rọ́lu gbèsè, tó wá tọ́ka si ìkéde ìjọba àpapọ̀ gẹ́gẹ́bí ohuntí kò bójúmu.

Diẹ nínú àwọn ọlọ́kọ̀ tó fi àidúnú wọn hàn lórí ọ̀rọ̀ owó epo yi ni ó yẹkí ìjọba fọ̀rọ̀ tó àwọn alágbàtà epo létí sáajú ìkéde àdínkù owó epo.

Méjì nínú wọn, ọ̀gbẹ́ni Adekọla John àti ọ̀gbẹ́ni Sulaiman Okebukọla ní ìgbésẹ̀ náà ni wọ́n gbọdọ̀ tètè bójútó láti mú àdínkù bá ìsoro táwọn èeyàn ńkojú.

Tawakalit Abiọla/Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *