Yoruba

Ọwọ́ Ilésẹ́ Ọlọ́pa Nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́ Tẹ Àwọn Jàndùkú Agbébọn Nílu Ìgàngàn

Ilésẹ́ ọlọ́pa n’ípinlẹ̀ Ọ̀yọ́ tifìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọwọ́ ti tẹ àwọn jàndùkú agbébọn mẹ́tàdínladọta nílu Ìgàngá n’ípinlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àwọn jàndùkú agbébọn ọ̀hún lọwọ́ àwọn ikọ̀ alábo tó ńgbogun ti ìwà ọ̀daràn, “Operation Burst” tẹ́ẹ̀.

Àwọn jàndùkú ọ̀hún t’ọ́wọ́ sìkún àwọn agbofinro tẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbọn àtàwọn ohun ìjà olóró min lọ́wọ́ wọn, niwọ́n f’ọwọ́ òfin mú nínú ọkọ̀ akérò kan.

Alukoro ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Olugbenga Fadeyi sọpé àwọn jàndùkú ọ̀hún ni ńse tọpinpin àwọn ajínigbé kan tíwọ́n fẹ́ gba owó idande lọ́wọ́ ẹbi ẹni wọn jígbé.

Ó fikun pé, ìwádi tó lórin ti bẹ̀rẹ̀, tíwọ́n si ti táàri àwọn tọ́wọ́tẹ̀ náà lẹsí ẹ̀ka tó ńrísí síse ìwádi ìwà ọ̀daràn ní Ìyàgankú.

Iyabọ̀ Adebisi/Elizabeth Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *