Ìjọba àpapọ̀ ńgbèrò láti kọ́ ọjà ìgbàlódé tíwọ́n yóò ti máà ta òkúta olówó iyebíye nílu ìbàdàn.

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti fi ilẹ̀ saréè méjì kalẹ̀ fún isẹ́ àkànse náà.

Alákoso fún ìdàgbàsókè ohun àlùmọ́nì, Ọ̀gbẹ́ni Ọlamilekan Adegbitẹ sọ èyí lágbègbè Ọjọọ, ní’jọba ìbílẹ̀ Akinyẹle níbi ayẹyẹ jíjọ̀wọ̀ ilẹ̀ ọ̀hún ńpèsè àwọn asojú ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Alákoso náà tọ́kasí pé, isẹ́ àkànse náà jẹ́ ara ìpinu ìjọba àpapọ̀ láti mú ètò ọrọ-ajé rẹ̀ bọ̀sípò lẹ́yìn ipa àrùn COVID-19.

Ọ̀gbẹni Ọlamilekan Adegbitẹ ẹnitó nírètí pé, isẹ́ àkànse náà yóò parí lọ́dún yíì, pẹ̀lú àlàyé pé kise àgbéga ètò ọrọaje nìkan nise àkànse náà yóò mu bá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, àmọ́ yóò tún fáà ojú àwọn olùdokowo mọ́ra.

Nínú ọrọ wọn, alákoso fọ́rọ̀ ohun àmúsagbára àti ohun àlùmọ́nì, Ọ̀gbẹ́ni Seun Ashamu àti alága àjọ tó ńrísí ìdàgbàsókè ohun àlùmọ́nì nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Abiọdun Oni sọpé ti isẹ́ àkànse náà báà parí yóò mu ìpinu ìjọba ti Gómìnà Seyi Makinde ńdarí se àseyọ́rí láti darí ètò ọrọ-ajé rẹ̀ sibomiran.

Iyabọ̀ Adebisi/Elizabeth Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *