Yoruba

O se Pataki ki ajosepo was laarin ijoba ni gbogbo eka ati ileese aladani lati mu ki amugbooro de ba nini anfani si eto ilera to koju owo.

Igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo lo soro yi lasiko to n siso loju ipade apero eto ilera alabode kan nilu Abuja.

Ojogbon Osinbajo tenumo pe ibasepo laarin ijoba nigbogbo eka, ni yoo wojutu si gbogbo ipenija to n suyo leka eto ilera alabode.

Ninu oro tie, alakoso feto isuna, Omowe Zainab Ahmed so pe ijoba apapo ni o fe ki eto ilera adojutofo kari gbogbo eeyan, papajulo awon to ku die kato fun.

                        Okareh/Afonja

Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti pàrọwà fáwọn onímọ̀tó láti ní ẹ̀mí ìgbọ́raẹniyé lórí bí wọ́n tise ńgberò àti bẹ́ẹ̀rẹ̀ síì gbowó padà lẹ́nu ìloro Lẹ́kkí.

Alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn nípinlẹ̀ Èkó ọ̀gbẹ́ni Gbenga Ọmọtọsọ ló pàrọwà yí nílu Èkó.

Ọgbẹni Ọmọtọsọ tẹnumọ́ ìdí tí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó fi gbọdọ̀ máà fojú áànu wo àwọn òsìsẹ́ ẹnu ìloro náà tí wọ́n o níse lówó fún bíì osù méjìdínlógún.

Ó ní ìwé tí ìjọba ńjá fáwọn olọ́kọ̀ èrò gẹ́gẹ́bí ara ìlànà àti bíjútó lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ àti láti fi sàfikún owó táwọn ìjọba ìbílẹ̀ ńpa, bákanáà ni yio mú àdíkùn ba bí ìkọlù se ńwáyé si wọn látọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́kọ̀ èrò.

Yẹmisi Owonikoko

Yoruba

Ọkọ̀ agbepo kan tó kún fún epo bẹntirol ti da ẹrù rẹ̀ nù lágbègbè Dangote, tó wà ní ìdígba Ilọra lópopónà másọsẹ̀ ọ̀yọ́ sí ìbàdàn, èyítí ó ti fi àwọn awakọ̀ àti olugbé ibẹ̀ sínú ewu.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria ríì gbọ́ wípé awakọ̀ epo nà ni wọ́n ti gbé lọ sí iléwòsàn lásìkò tó farapa bí ọkọ̀ náà ti fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ bó séè ńgbìyànjú àti bọ́ sóri títì másọsẹ̀ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ òní.

Àwọn èèyàn, ní páàpajùlọ àwọn ọlọ́kadà ni wọ́n yabo ibẹ̀ láti gbọ́n epo tí wọ́n sì ńsèdíwọ́ fáwọn òsìsẹ́ panápaná tí wọ́n fẹ́ dènà ìjànbá iná níbẹ̀.

Òsìsẹ́ ilé isẹ́ panápaná kan, ọ̀gbẹ́ni Jonhson Odewabi enití ó bá akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria sọ̀rọ̀ níbití ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé sọ èrò ọkàn rẹ̀ lórí iha tí àwọn èèyàn kò sọ̀rọ̀ ààbò.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria jábọ̀ wípé kòsí òsìsẹ́ aláàbo kankan níbi ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lásìkò tó ńkó ìròyìn jọ.

Ọga àgbà ilésẹ́ ọlọ́pa lẹ́kùn Ilọra, ọ̀gbẹ́ni Philip Abayọmi enití ó bá akọ̀ròyìn ilésẹ́ wa sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ sọ wípé àwọn òsìsẹ́ ilésẹ́ ọlọ́pa kò ní pẹ́ dé ibẹ̀.

Oguntọna/Yẹmisi Owonoko

Yoruba

Ẹgbẹ́ àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ lórí adójútófo nílẹ̀ yí CIIN ẹ̀ka tìpińlẹ̀ ọ̀yọ́ ti búra fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tuntun.

Ètò yí tó wáyé níbi ayẹyẹ ìfàmìẹ̀yẹ dáni lọ́lá àti ìgbaniwọlé ọlọ́lọọdún wọn tó wáyé nílu ìbàdàn ni wọ́n ti búra fún ọ̀gbẹ́ni Ọladeji Akinọla gẹ́gẹ́bí alága àti àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ mẹ́jọ min tí wọn yio tukọ̀ ẹgbẹ́ fún ọdun kan.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Akinọla sèlérí àti sisẹ́ lé àwọn àseyọrí tí àwọn tó ńfipò sílẹ̀ se, àti láti kọ́ olúlé ẹgbẹ́ fún ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ tìẹ, bàbá ìsàlẹ̀ ẹgbẹ́ náà, Olóyè Babajide Ọlatunde Agbeja rọ àwọn òsìsẹ́ elétò adójútófo láti máà tẹ̀lé àwọn ohuntí òfin isẹ́ wọn sọ kí wọ́n sì máà tètè san ẹ̀tọ́ àwọn oníbarà wọn tó yẹ.

Sáàjú ni alága níbi ayẹyẹ náà tíì sí igbákejì Gómìnà nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, Olóyè Iyiọla Ọladokun ẹnití olóyè Alani Ọlọjẹde sojú fún tẹnumọ́ ìdí tó fi sepàtàkì fáwọn ọmọ ilẹ̀ yí láti máà kówólé ètò adójútófo.

Lára àwọn ohuntí ó wáyé níbi ayẹyẹ náà láti fifi àmì ẹ̀yẹ dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó peregedé àti àwọn tó ti làmì láàka láwùjọ lọ́lá.

Kehinde Mosọpẹ/Yẹmisi Owonoko

Yoruba

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa lókèèrè, ẹ̀ka ti orílẹ̀ èdè Hungary, ọ̀mọ̀wé Hussaini Argungun ti bèèrè fún àtìlẹyìn ilésẹ́ ìjọba àpapọ̀ fọ́rọ̀ amujo ìjàmbá àti mímú ìdẹ̀rùn bá ará ìlú lórí àwọn akẹ́kọ ọmọ olẹ̀yí tí wọ́n sá kúrò ní Ukraine kí wọ́n báà le dúró ní Hungary.

Ọmọwe Argungun ẹnití ó ńbá ilé ẹ̀kọ́ gíga kan nílẹ̀ Hungary sisẹ́ ní ẹgbẹ́ àwọn ti ńpín óunjẹ fáwọn akẹ́kọ náà pẹ̀lú àtìlẹ́yì oníruru àwọn àjọ tí kíìse tìjọba.

Gẹ́gẹ́bí ọmọbíbí ìpínlẹ̀ Kẹbbi náà sesọ ótó igba àwọn akẹ́kọ náà tí wọ́n padà sí Nàijírìa ni wọ́n si ńretí kí wọ́n wá kó wọn ní Hungary, àmọ́ tó ní ọ̀pọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ náà ni wọ́n wà nípele tó kẹ́yìn ẹ̀kọ́ wọn tí wọ́n ti ńkọ́ nípa ìmọ̀ ìsègùn tí wọ́n sì ti fífẹ́hàn àti dúró ní Hungary pẹ̀lú ìrètí wípé àwọn ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ náà yio gbà wọn láti pári.

Ọmọwe Argungun fikún wípé àwọn kan nínú àwọn akẹ́kọ náà ni wọ́n ńfarapamọ́ sáwọn ilé ìjọsìn, àti àwọn ilégbe min táwọn àjọ tí kiise tìjọba pèsè.

Níbàyí náà, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ tí wọ́n sá kúrò ní Ukraine, Philip Bankọle tíì se akẹ́kọ ìpele tó kẹ́yìn inú ìmọ̀ ìsègùn ni kiev sọ wípé ìrètí òun ni láti parí ẹ̀kọ́ òun kí òun tó padà wa sílẹ̀ yí.

Ọgọọrọ àwọn akẹ́kọ ọmọ ilẹ̀ yí tí wọ́n sá lọ sí Poland, Hungary àti Romania ni wọ́n ti gbé wá padà sílé láti ìgbàtí ogun ti bẹ́ sílẹ̀ ní Ikraine.

Oluwayemisi Owonikoko

Yoruba

Àbá òfin láti sàyípadà ilé ẹ̀kọ́ gíga ìmọ̀ ẹ̀rọ Ládòkè Akintọla, LAUTECH, sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ńkọ́ ìmọ̀ gbogbogbò ni wọ́n ti kà fún ìgbà kejì nílé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ́ ọ̀yọ́.

Èyí ló jẹ́ nítorí ìwé kan tí Gómìnà Seyi Makinde fi sọwọ́ sílé ìgbìmọ̀ asòfin tí adarí ilé, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin kà níbití Gómìnà ti ńbèèrè fún àyípadà ilé ẹ̀kọ́ gíga ọ̀hún.

Nígbàtí wọn ńjìròrò lórí àbá òfin náà asòfin tó ńsojú ẹkùn àríwá Ògbómọ̀sọ́, Arábìrin Ọlawunmi Ọladeji ní orúkọìlú tó gba ilé ẹ̀kọ́ náà lálejò gbódọ̀ hàn nínú orúkọ rẹ̀ bí wọ́n se fẹ sọ ilé ẹ̀kọ́ gíga náà di elékan kan.

Ó wá dába kí wọ́n sọ́ọ̀ ní ilétẹ́kọ gíga Ladoke Akintọla, Ògbómọ̀sọ́ dípò ilé ẹ̀kọ́ gíga Ladoke Akintọla lasán tí ẹ̀ka alásẹ dába.

Nígbàtí ó ńfèsì, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ní àbá òfin náà jẹ́ lára ìgbésẹ̀ ìjọba tó wà lóde báyi láti sàtúnse ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Mosope Kehinde/Oluwayemisi Owonikoko  

Yoruba

Àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó, FRSC, ti ní lílo ìlànà ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé tí múkí ọwọ́ isẹ́ túbọ̀ yá kánkán àti jáfáfá síì léyití ó ti jẹ́kí àdínkù dé bá àwọn ìjàmbá ojú pópó.

Ọga àgbà àjọ FRSC, ọ̀mọ̀wé Boboye Oyeyẹmi ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ níbi ìdánilẹ́kọ kan tó wáyé nílu Abuja.

Ọmọwe Oyeyẹmi wá tẹ́ pẹpẹ oníruru ọ̀nà tí àjọ náà ti sàmúlò ìlànà ìgbàlódé nínú ìgbà sísẹ́ rẹ̀ láyití ó ní nínú ẹ̀rọ tí yio jẹ́kí wọ́n máà léè wòye bí àwọn ọkọ̀ tise ńsáré lójú pópó àti síse ìwé àsẹ ìwakọ̀ lọ́nà ìgbàlódé.

Ó wá wòye pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ yí ni wọ́n o tẹ́wọ́ gba àyípadà tó ńbá ọ̀nà ìgbà sisẹ́ wọn àmọ́ tí àjọ náà ti ńlawọn lọ́yẹ̀ lórí ìdí tó fi se pàtàkì láti fáàyè gba àyípadà rere.

Oluwayemisi Owonikoko

Yoruba

Àarẹ orílẹ̀dè yíì, Muhammadu Buhari ti sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, ìsèjọba òun ti n wójùtú sọ́rọ̀ ilégbe fáwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì, papajùlọ àwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńlánlá.

Lákokò tó ń sèfilọ́lẹ̀ àwọn isẹ́ àkànse ilégbe, abala àkọ́kọ́ nílu Òsogbo, tí sólùlú ìpínlẹ̀ Ọsun, áàrẹ sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà.

Áàrẹ Buhari ẹnití alákoso fọ́rs abẹ́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla sujúfún tọ́kasi pé, ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ńlánlá náà lójẹ́ pé wọ́n ti kún àkúnfàya léyi tó lòdìsí ètò ìlera tó múná dóko, ìdí sìnìyí, tí sèjọba rẹ̀ fi gùnlé isẹ́ àkànse kíkọ́ ilégbe tí yóò rọrùn.

Àarẹ kò sài fikun pé, ọ̀kan pàtàkì ni isẹ́ àkànse òhun jẹ́ lára àwọn ọ̀nà tísèjọba òun ti piyamọ kalẹ̀, láti mú ìgbéayé rọrùn fáwọn èèyàn , gẹ́gẹ́ olókóòwò kékèké àti talábọ́dé ló gba ise àkànse ilé kíkọ́ náà.

Ó ní isẹ́ àkànse ilé kíkọ́ náà ti fún ìjọba àpapọ̀ lánfàní nínú àwọn ìlérí tó ti se tẹ́lẹ̀ se, nípasẹ̀ pípèsè ilégbe fáwọn ikọ̀ agbábbọ̀ọ̀lù Super Eagles lẹ́yìn tíwọ́n jawé olúborí níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ adúláwọ̀ tọdún 1994 èyí tó mú àseyọ́rí bá ìjọba níwọ̀n ko ti se àmúsẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, náà, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọsun, ọ̀gbẹ́ni Adegboyega Oyetọla dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ ìjọba àpàpọ̀, tún  ise àkànse ọ̀hún èyí tóní yóò sàtìlẹ́yìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Ọsun láti pèsè ibùgbé tówó rẹ̀ kòní gunpá fáráàlú rẹ̀.

Net/Wojuade   

Yoruba

Agbẹjọ́rò kan, ọ̀mọ̀wé Kazeem Olaniyan ti gbàwọn  ọmọ ilé- ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ níyànjú láti tọwọ́ òfin tóníse pẹ̀lú káwọn asojú kan bo somun bọnú àtúnse ìwé òfin tónlọ lọ́wọ́.

Ọmọwe Ọlaniyan tótún jẹ́ olúkọ̀ lẹ́ka tíwọ́n tin kọ́ nípa ìmọ̀ òfin nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìbàdàn ló gbọ̀rọ̀ àmọ̀ràn yíì kalẹ̀ lákokò tó ń kópa lórí ètò ilé-isẹ́ Radio Nigeria kan lédè gẹ́ẹ̀sì, tamọ̀sí Straight Talk, níkànì Premier F.M 93.5.

Ó sàlàyé pé, àgbékalẹ̀ irúfẹ́ òfin bẹ́ẹ̀ sepàtàkì nítorí báwọn Gómìnà kan se ńkúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú tó fìbò wọn gbéwọn dépò, nítorí bí òfin se dákk lórí ohun tó tako ìgbésẹ̀ wọn ọhun.

Ọmọwe Ọlaniyan tún fikun pé, ìbó tó yan Gómìnà yóòwù, àtinú ẹgbẹ́ òsèlú rẹ̀ lótiwá, nítorí náà níkò fi bójumu fúnrúfẹ́ Gómìnà bẹ́ẹ̀ láti kúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú rẹ̀ bọ́sínú omin-in.

Kò sài tún sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, ìgbésẹ̀ àwọn asòfin ìpińlẹ̀ Eboyin tíwọ́n kúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú wọn pẹ̀lú Gómìnà David Umahi lòdì sófin, tíwọ́n si n fọwọ́ pa idà òfin lójú.

Kehinde/Wojuade

Yoruba

Ona gbogbo to dari si gbongan isembaye ilu Ibadan tii se Mapo lawon to ba fe gba ibe koja gbodo wa ibo miin gba nipa bi Olubadan Keilelogoji (42), oba Lekan Balogun yoo se maa gba ade lola.

Eyi lo jeyo laodo ajo to n ri si igbokegbodo oju opop nipinle Oyo OYRTMA ninu atejade ti gbimo alase ajo naa fi sita.

Gbogbo awon ona yi ni yoo je titipa losan oni, ti won yoo sisis awon one naa pada lojo Abameta.

Awon opopona toro kan ni ikorita Beere lo si gbonga Mapo, ikorita Born Photo lo si Ojaaba, ikorita idi Arere lo si Ojaaba ati Itamerin koja si Gbongan Mapo.

Atejade naa soo di mimo pegbogbo awon agbofinro lo ti wa nikaoe lati fir ii daju per eto irinna je gaare.

O tun ro awon araalu pe ki won fowosowopo pelu awon agbofinro lati fir ii daju pe ayaya naa lo nirowo rose.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Awon omo ile Nigeria ti kesi ijoba apapo ati ajo elepo robi NNPC pelu gbogbo awon toro kan leka epo robi ati afefe gaasi pe ki won rii daju pe epo petirolu po yannturu fun lilo araalu.

Won foju oro yi lede lasiko ti akoroyin Radio Nigeria n to pinpin ibi ti inkan de duro lawon ileepo to wa nigboro ilu Ibadan tii se Olu ilu Ipinle Oyo.

Meji lawa awon eeyan naa, ogbeni Dayo Ogunsola ati Ogbeni Aderemi Sekoni salaye wi pe bi ero se n po lawon ileepo lati bii osunkan jakelado ile yi lo ti n dinku.

Won tenumo pe, bi o tile je, pe ko se bee si ato fimulemu mo lawo ileepo kan ti won ti n ta jala epo petrol kan ni igba naira, N200, si okoolerugba naira, N220.

Won wa kesi awon to wa nidi ero akoso epo robi ati afefe gaasi pe ki won tenpele mo ojuse won, nipa fifi kele ofin gbe ileepo to ba n ko epo pamo tabi taa koja iye tijoba fowosi.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Aare Orileede yi, Mohaamadu Buhari ti fi aidunu re han lori bawon iko olote kan se lo dode awon eso alaabo oru, eyi to yo ri si biwon se sekupa die lara won nijoba ibile Sakaba Wasagu nipinle Kebbi.

Eyi lo jeyo ninu atejade kan toluranlowo Pataki fun Aare loro iroyin ati ibaraeni soro, Mallam Garuba Shahu fowosi pelu sisapejuwe isele naa gege bi eyi tiko bojumu.

Aare Buhari wa fowo idaniloju soya fawon omo orileede yipe isejoba oun yoo sa gbogbo agbara re lati ripe opin de ba iko olote debi to lapere yika orileede yi.

O wa pase fun gbogbo awon ajo alaabo lati fikun akitiyan won lori biba erongba awon agbe sumomi naa je ko to dipe won kolu awon eeyan.

Aare Buhari kedun pelu ebi awon eeyan to lugbadi ikolu naa.

NET/WOJUADE

Yoruba

Oludari ajo abo ara eni laabo ile, Nigeria Security and Civil Defence Corps, NSCDC, eka tipinle Oyo, Ogbeni Michael Adaralewa ti sefi lole iko kan ti yoo maa gbogun ti awon ayederu eso alaabo.

Iko amuseya naa, niwon mu won lati eka aladani tiwon je akosemose osise, alaabo nile yi, eka tipinle Oyo.

Nibi ifilole Iko amuseya naa, Ogbeni Adaralewa fimo awon omo egbe ohun lati karamasiki mo ise tiwon gbele won lowo, nibanu pelu ohun tiwon to e gbewon kale, lati forwo kilanko awon ayederu eso alaabo kuro ninu awon ewo alaabo tiwon je ojulowo nipinle Oyo.

O wa sekilo fawon eeyan awujo, lati ye maa lo soro awon eso alaabo ti ko ni iwe ase isise tabi ni akosile kenikeni lodo awon ajo torokan, lti dena isele ijinigbe, ifipa balopo to fimawon alonilowogba.

Folakemi Wojuade

Yoruba

Ijoba apapo si so pe oun koni faye gba gbigba awon eeyan nile Nigeria gegebi ajagun oke okun lo si ile Ukraine.

Gegebi atejade eyi ti agbenuso ti alakoso foro okeere, Francisca Omayuli fowosi ijoba lo ti n ni ajosopo pelu ile Ukraine lati le da irufe igbese be duro.

Atejade naa lo waye leyin ti aheso oro kan nja pea won eeyan nile yi to finu fido jowo are won lati darapo ileese ologun Ukraine, ni won n gba wole ni ileese Ukraine to wa nilu Abuja.

Nibayinaa, ileese Ukrain to w anile yi ti so pe, ko si ooto ninu pe won ti gba ologun lati ile miran, amo ti won fidi re mule pea won eeyan ile Nigeria kan ti wa si ileese naa lati so pea won ti setan lati satileyin fun Ukraine ninu aida ojuja ko Russia.

NET/Afonja

Yoruba

Awon toro eko gberu ti tenumo mimu eto eko omobinrin ni dandan.

Won soro amoran yi lasiko idanilekmo lati fi samin agbega omowe Morufat Balogun, tile eko giga versity Ibadan si ojogbon nipa Genetics.

Okan lara awon to gbe idanileko kale ti se olukoni lati ile eko giga Versity Ipinle Eko, LASU, Omowe Khadijat Shobowale so pee to eko se Pataki fun idagbasoke orile ede pelu atokasi pe asa, ati ise lawujo, lo n pagidana eto eko awon omobinrin.

Bakanna Oga agba eka ti won ti n ko nipa ise on anile eko giga Versity Ibadan, Ojogbon Afis Oladosu, sope aye ti kuro ni ko nima fi owo yepere mu awon obinrin, idi niyi to fiye ki itoju to peye wa lori won.

Alaga, nibi eto ohun, tit un se oga agba fajo JAMB, Ojogbon Ishaaw Oloyede tenumo pe ose Pataki lati ran awon omobinrin lo sileewe lati le de ibi to lapere laye.

Aya Igbakeji Gomina Nipinle Oyo, Ojogbon Hamdalat Olaniyan sapejuwe Ojogbon Balogun, gegebi akinkanju obinrin to feran omoniyan.

Oko eni to n se ayeye igbega to tun je agbenuso fun ileese to n risi oro awon eeyan ile yi to w anile okeere, Alhaji Abdul Rahman Balogun, tunmo idi Pataki to ti ye ki loko-laya, ma se atileyin fun ra won ki won le na aseyori.

Ninu oro Ojogbon Morufat Balogun nigbato n mo riri awon to wa nibi eto naa ro won ati ma se atileyin fun molebi won ninu ise ti wa bay an layo.

Eto naa ni awon toro eto kan gbongbo, awon akosemose nilese igbohun safefe, awon akeko to fi mo egbe Islam loniruuru, peju pese si.

Ibomor/Afonja

Yoruba

Ile Igbimo Asofin ile Nigeria ti fun awon ijoba ibile nile yi lominira eto enawo jakejado ile Nigeria pelu bo se pari agbeyewo ofin odun 1999.

Awon asofin ile igbimo asofin mejeeji ni won dibo lori aba ofin mejidinlaadorin pelu bi won se foowo si awon kan ti won si satako sawon min.

Ninu ibo won ni won ti fowosi ofin to n faaye gba oludije ti o si labe asia egbe oselu ti won sit un fowosi bi won se gbe ofisi agbejoro agba ile yi kuro nile ise eto idajo.

Bankan naa lawon asofin ohun dibo tako kawon to n dari ile igbimo asofin maa gba owo ifehinti ti won si tun tako aba ofin ti won gbe kale lori sise igbelaruge didasi eto oselu awon obinrin ile Nigeria.

Nigba to nsoro, aya igbakeji aare ileyi, arabinrin Dolapo Osinbajo tohun naa wa ni bi ijoko ile, salaye pe bi won se tako ofin to ro mo awon obinrin kiise ipe fun fifaaye gba awon obinrin ile yi.

 Blessing Okareh/Ayodele Olaopa

Yoruba

 Oga agba yanyan fun ile ise Olopa ile Nigeria, Ogbeni Usman Baba ti sekilo fawon osise olopa lati jina si lilo anfani awon ibudo ayewo oju ona ati didekun awon odaran fun gbigba owo abetele.

Ogbeni Baba to sekilo naa loluu ile ise olopa nilu Abuja fun awon logaloga agbegbe ati elekunjekun to fimo awon iko to n dekun iwa odaran.

O salaye pe ko ye kise won gegebi eso alaabo ma ko nira baa won onimoto atawon omo ileyi min to n pa o fin mo.

O wa ro won lati maa ri daju pe won sise won bi ise ki won si maa yago fun iwa gbigba owo lona aito lowo awon araalu.

Blessing Okareah/Ayodele Olaopa

Yoruba

Awon olugbe ilu’Badan ti kesi ijoba lati wojutu si owongogo epo pentrol to n faalee.

Won soro yi lasiko ti won n ba akoroyin ileese Radio Nigeria to n topinpin isele owongogo epo naa.Lara awon olugbe ohun, koroju si bawon ile epo se n ta oja, laarin igba naira si igba le ladota naira, eyi to yato gedegbe is iye jala epo kan tise marundinladosan naira.

Awako kan, Ogbeni Mukaila Oladimeji salaye pe ile epo ni oun sun si, koun le ri epo ra, bakanna olugbe meji miran, Ogbeni Ade Bola and Arabinrin Bola Adeoti sapejuwe owongogo epo gegebi inira ti ko se farada, pelu bawon se n ra epo lodo awon to n ta lona aito loju opopona.

Nibayinaa, owo oko lo ti lewo sii larin ilu Ibadan pelu ida ogoji ninu ogorun.

Okareh/Afonja

Yoruba

Lola ode yi, ireti w ape ijoba apapo yo bere si ni ko awon eeyan ile Nigeria to wa ninu rogbodiyan laarin Ukraine ati Russia wale.

Alakoso foro ile okere, Ogbeni Geaffrey Onyeama lo je koro yi di mimo lasiko ipade po pelu adari ile asofin agba, Ogbeni Femi Gbajabiamila.

Ogbeni Onyeama so pe gbigbe awon eeyan wale, ni yoo bere, kete ti are Muhammadu Buhari ba ti foun telu.

O se lalaye pe ile Ukraine, lo n jagun pelu Russia, ti oko ofurufu ko si lanfani loni to, amo igbese kiko awon eeyab ile yi wale ni won yo se lati awon ile to mule ti ile mejeeji ohun.

Alakoso foro ile okeere fikun pe ijoba apapo ni yoo pese oko ofurufu pelu atokasi pe iye awon eeyab ile yi ti won ba ti setan lati pada wale, ni won yo fi mo irufe baalu ti won yo lo

Okareh/Afonja

Yoruba

Lona ati wojutu si igbese iyanselodi, eyi tegbe awon osise lawon ile-eko giga fasity, Ile yii, ASUU, gunle egbe naa ati Ijoba Apapo orilede yii ti setan lati se ipade Lori iyanselodi ohun.

A o ranti pe, ojo aje tokoja legbe ASUU gunle iyanselodi olosu kan, eyi tiwon fi n kesijoba lati dahunsi ohun tiwon  n beere fun.

Atejade kan, tigbakeji oludari eka eto iroyin ati Oro to jemo awujo, Nile ise to n ri soro ise, ati igbanisise , Ogbeni Charles Akpan fisita lo ti so eyi di mimo , pelu alaye pe, alakoso foro ise ati igbanisise senito Chris Ngige ti sagbekale ipade kan pelawon to ntuko akoso egbe Asuu, lofisi re.

Net/ Wojuade

Yoruba

Iyawo Gomina Ipinle Oyo, Arabinrin Tamunominimi Makinde ti kesi awon omo ile Nigeria pe ki won dide atileyin fawon obinrin to lugbadi ijamba lasiko abe dida fomobirin.

Arabinrin Makinde soro imoran yi lasiko eto ayajo fifopin si abe dida fomobinrin fun todun yi.

Iyawo Gomina, eni ti alakoso akanse ise nipinle Oyo, Arabinrin Fausat Sanni soju fun tenumo pe ti atileyin ba n wa fun awon obinrin to ba lugbadi isoro lasiko abe dida, eyi yoo tun maa je ona itura fun ru awon ibisi ati onka omoniyan, Dokita Oladosu Ojengbede salaye wipe ipinle Oyo lo wa ni ipo keta awon ipinle to ni akosile isoro abe dida fun omobinrin o salaye wi pe, ipolongo atigbadegba to n lo lee mu adinku ba asa naa.

Alamojuto eto abe dida fomobinrin nipinle Oyo, Arabinrin Balqis Olawonyin naa salaye wipe awon Oloola to n dabe lona ibile lo ti n se ise papo pelu won lati fopin si asa naa.

Baba isale egbe awon oloola nile yi, Oloye Abiola Ogundokun naa salaye wi pe abe dida fomobinrin lewu ju anfani lo, o wa ro won pe ki won jawon ninu asa naa.

Awon to kopa nibi eto naa lo korajo latinu egbe bi PFN, FOMWAN, NASFAT, ati egbe awon agbebi ibile.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Ajo elepo robi nile yi ti soo di mimo wipe won ti da oko oju omi akeru nla marun to gbe eroja epo petrol to ni ethano laden marun pada, nigba ti won kefin pe eroja epo petirolu na ko koju osuwon.

Oludari agba ajo NNPC, Mebe Kyari lo foju oro yi lede lasiko to n farahan niwaju igbimo tee koto ile asofin keji to wa fun eroja epo robi lo ti salaye nipa bi nnkan se ri lori owongogo epo petrol to n ba ile yi finra lenu ojo meta yi.

O soo di mimo pe, ajo NNPC gan mo ipa eroja naa ti kop eye lara.

Ogbeni kyari salaye wipe, ajo na ko dunnu si isoro topo omo ile yi nkoju nipa epo buruku naa, o wa so asodaju pe isoro naa yoo je, rodo lo mumi nigba ti yoo ba fi di ose to on bo, pelu bi ajo naa se n tiraka lati se atunse si gbogbo asemose to ti waye.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Ilese to n risi iwole wode nile yii, NIS ti kede pe awon ti si oju opo eto iforukosile fun gbigba iwe irinna atowo sisan pada.

Eyi lo jeyo ninu atejade kan tagbemuso ibudo naa, Ogbeni Amos Okpu fisita nilu Abuja.

Oludari agba patapata fun Ajo ton risi iwole wode nile yii, Ogbeni Muhammadu Babandede, salaye pe oju opo naa yoo fawon eeyan laanfani lati beere fun nnkan ti won ba fe, kiwon si sanwo fokanojokan irufe iwe irinnaa tiwon bafe .

O fi kun kalaye re pe pelu bawon se si oju opo naa pada, ise gbigbawe irinaa ti bere niperewu lakotun pelu atokasi pe oju opo ero ayelujara ilese NIS, ti se www.immigration.gov.ng niwon yoo ti san owo.

Ao ranti pe, osu karun odun to koja lalakoso foro Abele, Ogbeni Rauf Aregbesola pase gbigbe oju opo ibudo naa ti pa, lona ati koju opo ohun tagere lawon ibudo ton pese iwe irinnaa naa yika orile ede yii.

Folakemi Wojuade/Olabiyi Fadahunsi

Yoruba

Olubadan tuntun omowe Lekan Balogun ti tewo gba iwe iyansipo gegebi Olubadan ile Ibadan.

Iwe iyansipo naa ni akowe agba fun ileese to wa for ijoba ibile ati oye jije nipinle Oyo, Omowe Bashir Olanrewaju fowo si.

Iiwe iyansipo naa ni Alaga Ijoba ibile Guusu Ilaaoorun Ibadan, Ogbeni Emmanuel Alawode mu lo sile Oluban tuntun to wa lagbegbe Alarere.

Iwe iyansipo naa ni won fi ki Olubadan tuntun ku orire peluadura pe ki Olorun fi Alafia ara pelu emi gigun to Oba tuntun naa lore lati fi dari ile Ibadan.

Fasasi/Saludeen

Yoruba

Egbe awon oluko ile eko giga fasiti nile yi, ASUU ti soo di mimo pe ajo to n seto idanwo ati wole sile eko giga (JAMB) lo leto lati maa set igbaniwole sawon ile eko giga.

Ninu atejade, eyi ti aare egbe ASUU, Ojogbon Emmanuel Osodeke fi sita lo ti salaye wipe igbese ajo JAMB lati maa seto liana igbani wole sile eko giga lo je ikoja aaye si Ominira ile eko giga fasiti.

O tenumo pe, ajo JAMB ko lagbara lato seto odiwon fun eni to koju osunwon lati wole sile eko giga fasiti tabi fagile illana eto eko nile eko giga fasiti.

Ojogbon Osodeke tun se afikun e wipe ojuse igbimo alase ile eko giga fasiti kookan ni lati se agbekale liana eto eko pelu liana igbaniwole sile eko giga fasiti won yala imo ijinle akoko tabi imo ijinle keji.

Fadahunsi/Salaudeen