Lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù yi ni àsekágbá ìdíje Best Ogedengbe láarin àwọn ogbábọ̀ọ̀lù tọ́jọ́ orí wọn kò kọjá ọdún mẹ́ẹ́dọgbọn wáyé.
Àwọn agbábọ̀ọ̀lù Adelagun Memorial Grammar School, Odinjo nílu Ìbàdàn àti Precing Footbal Academy, Ìdí-Ayùnrẹ́ ni yo gba ìdíje àsekágbá na.
Ìdíje náà ló bọ́ sí ìrántí ọdún kẹwa tí Best Ogedengbe tó jẹ́ asọ́lé fún ikọ̀ agbabọọlu Green Eagles dológbe, lósù kẹsan ọdún 2009.
Àbúrò Best Ogedengbe, Julius Ogedengbe sàlàyé pé, láti bí ọdún mẹ́fà sẹ́yìn ni wọ́n ti ń sétò ìdíje bọ́ọ̀lu na, nírantí rẹ̀.
Kemi Ogunkọla/Olaolu Fawọle